ÌBÉÈRÈ 6
Kí Ni Mo Lè Ṣe Káwọn Ojúgbà Mi Má Bàa Ba Ìwà Mi Jẹ́?
KÍ LO MÁA ṢE?
Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Bí Brian ṣe rí i tí méjì lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ń rìn bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lù kì-kì-kì. Lọ́sẹ̀ yẹn, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti fi sìgá lọ̀ ọ́. Ẹ̀ẹ̀kẹta tí wọ́n á fi lọ̀ ọ́ rèé.
Ọmọkùnrin àkọ́kọ́ sọ pé:
“Ìwọ nìkan lo tún wà ńbí ni? Jẹ́ n fi ọ̀rẹ́ mi kan hàn ẹ́.”
Bó ṣe sọ pé “ọ̀rẹ́”, bẹ́ẹ̀ ló rọra dẹ́ńgẹ̀, ló bá kọwọ́ bàpò tó sì ná kiní tá à ń wí yìí sí Brian.
Brian rí kinní ọ̀hún lọ́wọ́ ọmọ yìí, à ṣé sìgá ni! Bẹ́ẹ̀ làyà Brian tún lù kì-kì-kì.
Brian wá sọ pé: “Wò ó, mo ti sọ fún ẹ pé mi ò . . . ”
Ọmọkùnrin kejì bá já lu ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó ní: “Ìwọ tiẹ̀ ti lójo jù!”
Brian náà bá ṣe bí ọkùnrin, ó dá a lóhùn pé: “Mi ò kí í ṣojo!”
Ọmọkùnrin kejì bá fọwọ́ kọ́ Brian lọ́rùn, ó bá a sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́, ó ní: “Ṣebí wàá tiẹ̀ gbà á ná.”
Lọmọkùnrin àkọ́kọ́ bá tún na sìgá ọ̀hún sí Brian, ó wá sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ó ní: “A ò ní sọ fẹ́nì kankan. Gbà bí mo ṣe sọ fún ẹ, kò sẹ́ni tó máa mọ̀.”
Tó bá jẹ́ ìwọ ni Brian, kí lo máa ṣe?
RÒ Ó WÒ NÁ!
Ṣáwọn ọmọ kíláàsì Brian ti ro ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn dáadáa ṣá? Ṣé fúnra wọn ni wọ́n dìídì yàn láti máa fa sìgá? Kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó ní láti jẹ́ pé ṣe ni wọ́n jẹ́ káwọn èèyàn kó sí wọn lórí. Wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn gba tiwọn, torí ẹ̀ ni wọ́n ṣe gbà káwọn èèyàn máa pinnu ohun tí wọ́n á ṣe fún wọn.
Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, báwo lo ṣe lè dá yàtọ̀ káwọn ojúgbà ẹ má bàa kó ìwà tí ò dáa ràn ẹ́?
-
FOJÚ INÚ WO OHUN TÓ LÈ ṢẸLẸ̀
Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 22:3.
Lọ́pọ̀ ìgbà, o lè fojú inú yàwòrán ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o rí àwọn ọmọ iléèwé rẹ kan lọ́ọ̀ọ́kán níbi tí wọ́n kóra jọ sí, tí wọ́n sì ń fa sìgá. Tó o bá ti ronú ohun tí wọ́n lè sọ tàbí ṣe, wàá ti mọ ohun tó o máa ṣe tí wọ́n bá gbé wàhálà wọn dé.
-
RONÚ
Bíbélì sọ pé: “Ẹ di ẹ̀rí-ọkàn rere mú.”—1 Pétérù 3:16.
Bí ara rẹ pé, ‘Báwo ló ṣe máa rí lára mi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn tí mó bá lọ jẹ́ káwọn èèyàn mú mi ṣe ohun tí kò tọ́?’ Òótọ́ ni pé àwọn ojúgbà ẹ lè gba tìẹ fúngbà díẹ̀. Àmọ́, ǹjẹ́ o ò ní pa dà kábàámọ̀ rẹ̀ tó bá yá? Ṣé wàá gbàgbé irú ẹni tó o jẹ́ torí kó o lè tẹ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ lọ́rùn?—Ẹ́kísódù 23:2.
-
PINNU
Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n a máa ṣọ́ra.”—Òwe 14:16, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.
Bó pẹ́ bó yá, a máa ní láti ṣèpinnu, ibi yòówù kí ìpinnu tá a ṣe sì já sí, àwa fúnra wa la máa fàyà rán an. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tó ṣe ìpinnu tó dáa, àwọn bíi Jósẹ́fù, Jóòbù àti Jésù. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn bíi Kéènì, Ísọ̀ àti Júdásì, ìpinnu tí kò dára làwọn ṣe ní tiwọn. Ìwọ ńkọ́, kí lo máa ṣe?
Bíbélì sọ pé: “Máa fi ìṣòtítọ́ báni lò.” (Sáàmù 37:3) Tó o bá ti ro ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí, tó o sì ti pinnu ohun tó o máa ṣe, á rọrùn fún ẹ gan-an láti sọ fáwọn ojúgbà ẹ pé o ò ṣe, o ò sì ṣe náà nìyẹn, ìyẹn á sì ṣe ẹ́ láǹfààní.
Má làágùn jìnnà, kò dìgbà tó o bá kó àlàyé palẹ̀ fáwọn ojúgbà ẹ. Ṣáà ti sọ fún wọn pé o ò ṣe, kó o sì KỌ̀ jálẹ̀. Tàbí kẹ̀, kó lè yé wọn pé kì í ṣọ̀rọ̀ eré rárá, o lè sọ fún wọn pé:
-
“Ẹ má tiẹ̀ bá mi so ọ́ rárá!”
-
“Mi ò kí í ṣe irú ẹ̀!”
-
“Ó yẹ kẹ́ ẹ ti mọ̀ pé mi ò ní bá yín ṣe irú nǹkan bẹ́yẹn!”
Àṣírí ibẹ̀ ni pé kó o tètè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ò ṣe, kó o sì jé kó dá wọn lójú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á yà ẹ́ lẹ́nu pé ṣe làwọn ojúgbà rẹ á yáa fi ẹ́ sáyè ẹ, wọn ò tún jẹ́ yọ ẹ́ lẹ́nu mọ́!
OHUN TÓ O LÈ ṢE TÍ WỌ́N BÁ Ń FI Ẹ́ ṢE YẸ̀YẸ́
Táwọn ojúgbà ẹ bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ ńkọ́? Tí wọ́n bá sọ pé, “Kí ló tiẹ̀ ń ṣe ìwọ gan-an, àbí ẹ̀rù ń bà ẹ́ ni?” Kó o tètè yáa mọ̀ pé ìyẹn ti kúrò lọ́rọ̀ eré, wọ́n fẹ́ fipá mú ẹ ṣohun tí kò tọ́ nìyẹn. Kí lo wá lè ṣe? Ó kéré tán, ohun méjì wà tó o lè ṣe.
-
O lè pa yẹ̀yẹ́ ọ̀hún mọ́ra. (“O ríyẹn sọ, ẹ̀rù ń bà mí!” Kó o wá sọ ìdí tẹ́rù fi ń bà ẹ́ fún wọn ní ṣókí.)
-
O lè fún wọn lésì. Jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó o fi sọ pé o ò ṣe, kó o wá dọ́gbọ́n yọ ọ̀rọ̀ sí wọn lára, ìyẹn ọ̀rọ̀ táá mú kí wọ́n ronú. (“Èmi ò rò pé irú yín ló yẹ kó máa mu sìgá!”)
Táwọn ojúgbà ẹ bá ṣì ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́, tètè yáa bá ẹsẹ̀ rẹ sọ̀rọ̀! Má gbàgbé pé bó o bá ṣe pẹ́ lọ́dọ̀ wọn tó ni wọ́n á ṣe máa yọ ẹ́ lẹ́nu tó. Tó o bá tètè kúrò níbẹ̀, ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé o ò fẹ́ káwọn ojúgbà ẹ sọ ẹ́ dà bí wọ́n ṣe dà.
Òótọ́ kan tí ò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ni pé kò sí báwọn ojúgbà ẹ ò ṣe ní máa yọ ẹ́ lẹ́nu. Àmọ́, o lè pinnu ohun tó o máa ṣe, o lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ò ṣe, o ò sì ṣe náà nìyẹn, o sì lè bomi paná ẹ̀ bí wọ́n bá tún gbé wàhálà wọn dé. Torí náà, ọwọ́ ẹ ló kù sí!—Jóṣúà 24:15.