Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KEJE

Ó “Ń Bá A Lọ ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà””

Ó “Ń Bá A Lọ ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà””

1, 2. Báwo ni ipò nǹkan ṣe rí nígbà tí Sámúẹ́lì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀? Kí nìdí tí Sámúẹ́lì fi gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó máa mú kí wọ́n ronú pìwà dà?

SÁMÚẸ́LÌ ti jẹ́ wòlíì àti onídàájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Wòlíì olóòótọ́ yìí wá pe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ sí ìlú Gílígálì ní ìgbà ẹ̀rùn, tí àwọn àgbẹ̀ tó wà ní àgbègbè náà ti ń gbára dì láti máa kórè àlìkámà tó wà ní oko wọn. Lóde òní, oṣù May tàbí June nìyẹn máa jẹ́. Níbi tí Sámúẹ́lì dúró sí níwájú àwọn èèyàn náà, ó wò wọ́n lọ gààràgà. Kẹ́kẹ́ pa mọ́ gbogbo àwọn èèyàn náà lẹ́nu. Ó dájú pé Sámúẹ́lì ní ọ̀rọ̀ tó fẹ́ bá àwọn èèyàn náà sọ. Àmọ́, ọgbọ́n wo ló fẹ́ dá sí i tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ á fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn?

2 Àwọn èèyàn náà ò mọ wàhálà tí wọ́n fẹ́ kóra wọn sí. Wọ́n ní ó di dandan káwọn ní ọba tó jẹ́ èèyàn, táá máa ṣàkóso àwọn. Kò tètè yé wọn pé èyí ò fi ọ̀wọ̀ hàn fún Jèhófà Ọlọ́run wọn àti wòlíì rẹ̀. Ohun tó sì túmọ̀ sí ni pé wọ́n kọ Jèhófà ní Ọba wọn! Kí ni Sámúẹ́lì máa ṣe káwọn èèyàn yìí lè ronú pìwà dà?

Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí kọ́ nípa ìgbà ọmọdé Sámúẹ́lì táá jẹ́ ká ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, bá a tiẹ̀ ń gbé láàárín àwọn èèyàn burúkú

3, 4. (a) Kí nìdí tí Sámúẹ́lì fi sọ̀rọ̀ nípa ìgbà èwe rẹ̀? (b) Kí nìdí tí àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Sámúẹ́lì fi wúlò fún wa lónìí?

3 Sámúẹ́lì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Mo ti darúgbó.” Ewú orí rẹ̀ sì fi hàn pé òótọ́ ló sọ. Lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Èmi sì ti rìn níwájú yín láti ìgbà èwe mi títí di òní yìí.” (1 Sám. 11:14, 15; 12:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sámúẹ́lì ti darúgbó, kò gbàgbé ìgbà èwe rẹ̀. Ó ṣì ń rántí bí nǹkan ṣe rí nígbà náà dáadáa. Àwọn ìpinnu tó ṣe nígbà tó wà léwe ti mú kó gbé ìgbé ayé tó fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ àti pé ó jẹ́ olùfọkànsìn.

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Sámúẹ́lì gbé láàárín àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ tí wọn kò sì dúró ṣinṣin, ó ní láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ máa pọ̀ sí i. Bó ṣe rí lóde òní náà nìyẹn. Ó gba ìsapá ká tó lè ní ìgbàgbọ́, torí pé inú ayé oníwà ìbàjẹ́ táwọn èèyàn ò ti ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run là ń gbé. (Ka Lúùkù 18:8.) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ lára Sámúẹ́lì, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ọmọdé rẹ̀.

Ọmọdékùnrin Tó “Ń Ṣe Ìránṣẹ́ Níwájú Jèhófà”

5, 6. Kí ló mú kí ìgbà ọmọdé Sámúẹ́lì ṣàrà ọ̀tọ̀? Kí ló mú kó dá àwọn òbí rẹ̀ lójú pé ó ń rí àbójútó tó péye?

5 Ìgbà ọmọdé Sámúẹ́lì ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìdí sì ni pé kò pẹ́ tí wọ́n já a lẹ́nu ọmú tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sin Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn mímọ́ tó wà ní ìlú Ṣílò. Àgọ́ ìjọsìn yìí fi ohun tó lé ní ọgbọ̀n kìlómítà jìn sí ilé rẹ̀ ní Rámà. Ó ṣeé ṣe kó ti pé ọmọ ọdún mẹ́ta nígbà yẹn tàbí kó ti lé díẹ̀. Àmọ́ àwọn òbí rẹ̀, ìyẹn Ẹlikénà àti Hánà, ti fi gbogbo ọkàn wọn yọ̀ǹda rẹ̀ fún Jèhófà kó lè máa ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn gẹ́gẹ́ bíi Násírì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. * Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ńṣe làwọn òbí Sámúẹ́lì ta á nù torí pé wọn kò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?

6 Rárá o! Wọ́n mọ̀ pé ọmọ wọn á rí ìtọ́jú ní Ṣílò. Ó dájú pé Élì, tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà, bójú tó ọ̀ràn náà bó ṣe yẹ torí pé òun ni Sámúẹ́lì bá ṣiṣẹ́. Àwọn obìnrin kan tún wà ní àgọ́ ìjọsìn níbẹ̀ tí àwọn náà ń ṣe onírúurú iṣẹ́, ó sì dájú pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà létòlétò.—Ẹ́kís. 38:8; Oníd. 11:34-40.

7, 8. (a) Báwo ni àwọn òbí Sámúẹ́lì ṣe ń fi ìfẹ́ fún un ní ìṣírí lọ́dọọdún? (b) Kí làwọn òbí òde òní lè rí kọ́ lára àwọn òbí Sámúẹ́lì?

7 Ní àfikún sí ìyẹn, Hánà àti Ẹlikénà pàápàá ò gbàgbé Sámúẹ́lì, àkọ́bí wọn ọ̀wọ́n. Ó ṣe tán, òun ni Ọlọ́run fi dáhùn àdúrà wọn. Hánà tọrọ ọmọkùnrin lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì ṣèlérí pé òun á yọ̀ǹda ọmọ náà fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Tí Hánà bá ń lọ síbi àgọ́ ìjọsìn lọ́dọọdún, ó máa ń hun aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá, á sì mú un dání fún Sámúẹ́lì kó lè máa fi ṣiṣẹ́. Láìsí àní-àní, ọmọdékùnrin náà mọyì bí ìyá rẹ̀ ṣe máa ń bẹ̀ ẹ́ wò. Ó sì dájú pé bí àwọn òbí rẹ̀ ṣe ń fi ìfẹ́ fún un ní ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà ń ràn án lọ́wọ́ gan-an, torí ìyẹn ń jẹ́ kó rí i pé àǹfààní ńlá ni láti máa sin Jèhófà ní ibi tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yẹn.

8 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn òbí lè rí kọ́ lára Hánà àti Ẹlikénà lóde òní. Ó wọ́pọ̀ pé kí àwọn òbí gbájú mọ́ bí wọ́n ṣe máa pèsè ohun ìní tara fún àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n má sì fún bí wọ́n ṣe máa ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run ní àfiyèsí. Ṣùgbọ́n ohun tí àwọn òbí Sámúẹ́lì fi sí ipò àkọ́kọ́ ni àjọṣe ìdílé wọn pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn sì kó ìpa tó pọ̀ nínú irú ẹni ti ọmọ wọn jẹ́ nígbà tó dàgbà.—Ka Òwe 22:6.

9, 10. (a) Báwo ni àgọ́ ìjọsìn ṣe rí? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) Báwo ni ọ̀rọ̀ ibi mímọ́ náà ṣe rí lára Sámúẹ́lì tó jẹ́ ọmọdé? (b) Irú iṣẹ́ wo ló ṣeé ṣe kí Sámúẹ́lì máa ṣe? Ọ̀nà wo lo rò pé àwọn ọmọdé lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lóde òní?

9 Bí ọmọdékùnrin náà ṣe ń dàgbà, a lè ronú pa dà sí ìgbà tó wà lọ́mọdé, ká máa wo bó ṣe ń ṣeré káàkiri orí àwọn òkè kéékèèké tó yí Ṣílò ká. Bó ṣe ń wo ìlú àti àfonífojì tó wà ní apá kan láàárín àwọn òkè náà, ó ṣeé ṣe kí ọkàn rẹ̀ kún fún ayọ̀, kí orí rẹ̀ sì tún wú nígbà tó rí àgọ́ ìjọsìn Jèhófà. Ibi mímọ́ ni àgọ́ ìjọsìn yẹn ní tòótọ́. * Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó irínwó [400] ọdún tí Ọlọ́run ti sọ fún Mósè pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ ọ. Òun sì ni ojúkò kan ṣoṣo tó wà fún ìjọsìn mímọ́ Jèhófà ní gbogbo ayé.

10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọdé ni Sámúẹ́lì, ó fẹ́ràn àgọ́ ìjọsìn náà. A rí i kà nínú ìwé tó fọwọ́ ara rẹ̀ kọ nígbà tó dàgbà pé: “Sámúẹ́lì sì ń ṣe ìránṣẹ́ níwájú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ọmọdékùnrin kan, ó sán éfódì aṣọ ọ̀gbọ̀.” (1 Sám. 2:18) Aṣọ tí kò lápá ti Sámúẹ́lì máa ń wọ̀ yẹn fi hàn pé ó máa ń ran àwọn àlùfáà lọ́wọ́ nínú àgọ́ ìjọsìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sámúẹ́lì kì í ṣe ara ẹgbẹ́ àlùfáà, ara iṣẹ́ rẹ̀ ni pé kó ṣí àwọn ilẹ̀kùn àgbàlá àgọ́ ìjọsìn ní òwúrọ̀, kó sì máa ṣèránṣẹ́ fún Élì tó ti dàgbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbádùn àǹfààní tó ní níbi àgọ́ ìjọsìn yìí, nígbà tó yá ohun kan bẹ̀rẹ̀ sí í da ọkàn rẹ̀ láàmú. Ohun burúkú kan ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé Jèhófà.

Kò Lọ́wọ́ sí Ìwà Ìbàjẹ́

11, 12. (a) Kí ló burú jù lọ nínú ohun tí Hófínì àti Fíníhásì ṣe? (b) Irú ìwà burúkú àti ìwà ìbàjẹ́ wo ni Hófínì àti Fíníhásì hù nínú àgọ́ ìjọsìn? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

11 Nígbà tí Sámúẹ́lì wà lọ́mọdé, ó rí i táwọn èèyàn ń hu ìwà burúkú àti ìwà ìbàjẹ́. Élì ní àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n ń jẹ́ Hófínì àti Fíníhásì. A rí i kà nínú ìwé Sámúẹ́lì pé: “Àwọn ọmọkùnrin Élì jẹ́ aláìdára fún ohunkóhun; wọn kò ka Jèhófà sí.” (1 Sám. 2:12) Kókó méjì tó wà nínú ẹsẹ yìí tan mọ́ra. Hófínì àti Fíníhásì jẹ́ “aláìdára fún ohunkóhun,” tàbí lédè mìíràn, “àwọn ọmọ tí kò wúlò fún nǹkan kan,” torí pé wọn kò ka Jèhófà sí rárá. Ìlànà òdodo Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ò já mọ́ nǹkan kan lójú wọn. Èyí ló burú jù lọ nínú àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe, òun ló sì fa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yòókù tí wọ́n dá.

12 Òfin Ọlọ́run sọ iṣẹ́ tí àwọn àlùfáà á máa ṣe àti bí wọ́n á ṣe máa rúbọ nínú àgọ́ ìjọsìn rẹ̀. Ìyẹn sì yẹ bẹ́ẹ̀! Ìdí ni pé àwọn ẹbọ yẹn dúró fún àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn èèyàn kí wọ́n bàa lè mọ́ lójú rẹ̀, kí wọ́n sì lè rí ìbùkún àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Ṣùgbọ́n Hófínì àti Fíníhásì mú kí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlùfáà hùwà àìlọ́wọ̀ ńláǹlà sí àwọn ọrẹ ẹbọ náà. *

13, 14. (a) Báwo ni ìwà burúkú tí wọ́n hù nínú àgọ́ ìjọsìn ṣe nípa lórí àwọn tó ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run? (b) Báwo ni Élì kò ṣe ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi bàbá àti gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà?

13 Fojú inú wo ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì, bó ṣe ń wò ó tí ẹnikẹ́ni ò ṣàtúnṣe irú àwọn ìwà tó burú jáì bẹ́ẹ̀! Ọ̀pọ̀ èèyàn, tó fi mọ́ àwọn tálákà, àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àti àwọn tí ojú ń pọ́n, ni wọ́n ń wá síbi àgọ́ ìjọsìn mímọ́ yẹn kí wọ́n lè rí ìtura àti okun tẹ̀mí gbà. Ṣùgbọ́n mélòó mélòó lára wọn ni Sámúẹ́lì rí tí wọ́n ń pa dà sílé wọn láìrí ìtura tí wọ́n ń wá, pẹ̀lú ọgbẹ́ ọkàn, tàbí ìtìjú? Báwo ló sì ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó mọ̀ pé Hófínì àti Fíníhásì ń bá àwọn kan lára àwọn obìnrin tí wọ́n ń sìn nínú àgọ́ ìjọsìn lò pọ̀, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣàì ka òfin Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ sí? (1 Sám. 2:22) Ó ṣeé ṣe kó retí pé Élì máa wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà.

Ìwà burúkú táwọn ọmọ Élì ń hù ti ní láti kó ìdààmú bá Sámúẹ́lì gidigidi

14 Élì ló tọ́ sí jù lọ láti bójú tó ìṣòro tó ń peléke sí i yìí. Gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, òun ló máa jíhìn fún ohun tó bá ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ ìjọsìn. Òun ni bàbá àwọn ọmọ náà, ojúṣe rẹ̀ sì ni pé kó tọ́ wọn sọ́nà. Ó ṣe tán, wọ́n ń ṣèpalára fún ara wọn àti àwọn èèyàn míì tí kò lóǹkà ní ilẹ̀ náà. Àmọ́, Élì kò ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi bàbá àti àlùfáà àgbà. Ńṣe ló kàn bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí lọ́nà yọ̀bọ́kẹ́. (Ka 1 Sámúẹ́lì 2:23-25.) Àmọ́ ìbáwí tó le gan-an ló yẹ kó fún àwọn ọmọ náà. Ó ṣe tán, ẹ̀ṣẹ̀ tó yẹ fún ikú ni wọ́n ń dá!

15. Ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tó lágbára wo ni Jèhófà ní kí wòlíì rẹ̀ lọ sọ fún Élì? Kí sì ni ìdílé Élì ṣe lẹ́yìn ìkìlọ̀ náà?

15 Ọ̀ràn náà burú débi tí Jèhófà fi rán “èèyàn Ọlọ́run kan,” ìyẹn wòlíì kan tí Bíbélì kò sọ orúkọ rẹ̀, pé kó lọ sọ ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tó lágbára fún Élì. Jèhófà sọ fún Élì pé: “O . . . ń bọlá fún àwọn ọmọkùnrin rẹ jù mí.” Torí náà, Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ọjọ́ kan náà làwọn ọmọ burúkú tí Élì bí máa kú àti pé ìdílé Élì yóò jẹ palaba ìyà, ipò iyì tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ àlùfáà sì máa bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ǹjẹ́ ìkìlọ̀ tó lágbára yìí mú kí nǹkan yí pa dà nínú ìdílé náà? Ìtàn náà kò sọ pé wọ́n yí ọkàn pa dà.—1 Sám. 2:27–3:1.

16. (a) Bí Sámúẹ́lì tilẹ̀ jẹ́ ọmọdé, kí ni Bíbélì sọ fún wa nípa bó ṣe ń tẹ̀ síwájú? (b) Ṣé ohun tí Bíbélì sọ nípa Sámúẹ́lì mú ẹ lọ́kàn yọ̀? Ṣàlàyé.

16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọdé ni Sámúẹ́lì, ipa wo ni gbogbo ìwà ìbàjẹ́ yìí ní lórí rẹ̀? Láìka bí ìtàn yìí ti bani nínú jẹ́ tó, ìròyìn rere nípa bí Sámúẹ́lì ṣe ń dàgbà tó sì ń tẹ̀ síwájú ń fúnni láyọ̀. Rántí pé nínú 1 Sámúẹ́lì 2:18, a kà nípa Sámúẹ́lì pé ó ń fi ìṣòtítọ́ “ṣe ìránṣẹ́ níwájú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ọmọdékùnrin.” Kódà, bí Sámúẹ́lì ṣe kéré tó yẹn, ó gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run. Ohun kan tó túbọ̀ múni lọ́kàn yọ̀ wà ní orí kan náà yẹn, ní ẹsẹ 21. Ó ní: “Ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ ní dídàgbà lọ́dọ̀ Jèhófà.” Bó ṣe ń dàgbà ni àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Baba rẹ̀ ọ̀run ń lágbára sí i. Irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ló ń dáàbò boni jù lọ lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́ èyíkéyìí.

17, 18. (a) Dípò kí àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni hùwà ìbàjẹ́, báwo ni wọ́n ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì? (b) Kí ló fi hàn pé ohun tó tọ́ ni Sámúẹ́lì yàn láti ṣe?

17 Ì bá ti rọrùn fún Sámúẹ́lì láti ronú pé bí àlùfáà àgbà àtàwọn ọmọ rẹ̀ bá jọ̀wọ́ ara wọn fún ẹ̀ṣẹ̀, òun náà lè máa ṣe ohun tó wu òun. Àmọ́, bí àwọn èèyàn bá ń hùwà ìbàjẹ́, tó fi mọ́ àwọn tó wà nípò àṣẹ, ìyẹn ò tó láti mú ká máa dẹ́sẹ̀. Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì, wọ́n sì ń bá a lọ ní “dídàgbà lọ́dọ̀ Jèhófà,” kódà bí àwọn kan tó yí wọn ká kò bá tiẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀.

18 Kí wá ni àbájáde bí Sámúẹ́lì ṣe yàn láti ṣègbọràn sí Jèhófà? Bíbélì sọ pé: “Ní gbogbo àkókò yìí, ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì ń dàgbà sí i, ó sì túbọ̀ ń jẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn ní ojú ìwòye Jèhófà àti ti àwọn ènìyàn.” (1 Sám. 2:26) Torí náà, bí àwọn kan ò bá tiẹ̀ fẹ́ràn Sámúẹ́lì, àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn fẹ́ràn rẹ̀. Jèhófà pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ọmọdékùnrin yìí torí pé ó ń ṣe ohun tó tọ́. Sámúẹ́lì sì mọ̀ dájú pé Ọlọ́run máa mú gbogbo ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ ní Ṣílò kúrò, àmọ́ ó lè máa ṣe kàyéfì nípa ìgbà tó máa jẹ́. Lálẹ́ ọjọ́ kan, Sámúẹ́lì rí ìdí tí kò fi yẹ kó ṣe kàyéfì mọ́.

“Sọ̀rọ̀, Nítorí Tí Ìránṣẹ́ Rẹ Ń Fetí Sílẹ̀”

19, 20. (a) Ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sámúẹ́lì lóru ọjọ́ kan nígbà tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn. (b) Kí ló fi hàn pé Sámúẹ́lì bọ̀wọ̀ fún Élì? Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe wá mọ ibi tí ohùn tó ń gbọ́ ti wá?

19 Kí ilẹ̀ tó mọ́, iná fìtílà ńlá tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn ṣì ń jó lọ́úlọ́ú. Bí gbogbo nǹkan ṣe pa rọ́rọ́ tó níbẹ̀, Sámúẹ́lì gbọ́ ohùn kan tó ń pe orúkọ rẹ̀. Ó rò pé Élì tó ti darúgbó tí ojú rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ ríran mọ́ ló ń pe òun. Sámúẹ́lì dìde, ó sì “sáré lọ” bá bàbá arúgbó náà. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ọmọ yìí ṣe ń sáré lọ láì wọ bàtà kó lè mọ ohun tí Élì ń fẹ́ tó fi pè é? Ó wúni lórí pé Sámúẹ́lì bọ̀wọ̀ fún Élì ó sì ń ṣe inú rere sí i. Láìka gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Élì sí, òun ṣì ni àlùfáà àgbà tí Jèhófà yàn.—1 Sám. 3:2-5.

20 Sámúẹ́lì jí Élì, ó sì sọ fún un pé: “Èmi nìyí, nítorí tí ìwọ pè mí.” Àmọ́ Élì sọ pé òun kò pè é, ó sì ní kí ọmọdékùnrin náà pa dà lọ sùn. Síbẹ̀, Sámúẹ́lì tún gbọ́ ohùn náà ní ìgbà méjì sí i! Níkẹyìn, Élì mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Nígbà yẹn, ó ṣọ̀wọ́n kí Jèhófà bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ yálà nípasẹ̀ ìran tàbí àsọtẹ́lẹ̀, kò sì ṣòro láti mọ ìdí tí ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, Élì mọ̀ pé Jèhófà ti ṣe tán láti máa tipasẹ̀ ọmọdékùnrin yìí bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀! Élì ní kí Sámúẹ́lì pa dà lọ sùn, ó sì sọ fún un bó ṣe yẹ kó dáhùn tó bá tún gbọ́ ohùn Jèhófà. Sámúẹ́lì ṣègbọràn. Kò sì pẹ́ tó fi gbọ́ ohùn náà tó ń ké sí i pé: “Sámúẹ́lì, Sámúẹ́lì!” Ọmọdékùnrin náà dáhùn pé: “Sọ̀rọ̀, nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń fetí sílẹ̀.”—1 Sám. 3:1, 5-10.

21. Báwo la ṣe lè fetí sí Jèhófà lónìí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

21 Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Jèhófà ní ìránṣẹ́ kan ní Ṣílò tó ń fetí sí i. Bí Sámúẹ́lì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sí ohùn Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nìyẹn o! Ṣé ìwọ náà ń fetí sí ohùn Jèhófà nígbà gbogbo? Àmọ́, kò dìgbà tí ohùn kan bá bá wa sọ̀rọ̀ látọ̀run lóru o! Lóde òní, ìgbàkigbà la lè gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ó ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí a bá ṣe túbọ̀ ń fetí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń ṣe ohun tó fẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa á ṣe máa pọ̀ sí i. Ohun tó mú kí ìgbàgbọ́ Sámúẹ́lì náà pọ̀ sí i nìyẹn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ba Sámúẹ́lì, kò fà sẹ́yìn láti sọ fún Élì nípa ìdájọ́ tí Jèhófà ń mú bọ̀ wá sórí rẹ̀

22, 23. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ ba Sámúẹ́lì lẹ́rù láti sọ fún Élì ṣe ní ìmúṣẹ? (b) Irú èèyàn wo làwọn èèyàn túbọ̀ ń mọ Sámúẹ́lì sí?

22 Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì ni ohun tó wáyé ni Ṣílò lálẹ́ ọjọ́ yẹn jẹ́ fún Sámúẹ́lì. Ọjọ́ yẹn ló bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà, ó sì di wòlíì Ọlọ́run àti agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀. Ẹ̀rù kọ́kọ́ ba ọmọdé náà láti jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an sí Élì. Ìdí ni pé ohun tó fẹ́ sọ jẹ́ ìkéde tó kẹ́yìn pé ohun tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìdílé Élì máa tó ní ìmúṣẹ. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì fi ìgboyà jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an, Élì náà sì fìrẹ̀lẹ̀ gba ìdájọ́ Ọlọ́run. Kò pẹ́ tí gbogbo ohun tí Jèhófà sọ fi ní ìmúṣẹ. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn Filísínì jagun, àwọn Filísínì sì pa Hófínì àti Fíníhásì lọ́jọ́ kan náà. Élì náà kú nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti gba Àpótí Ẹ̀rí Jèhófà.—1 Sám. 3:10-18; 4:1-18.

23 Àmọ́, ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń mọ Sámúẹ́lì sí wòlíì olóòótọ́. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀.” Ó tún fi kún un pé Jèhófà ò jẹ́ kí èyíkéyìí lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Sámúẹ́lì lọ láìní ìmúṣẹ.—Ka 1 Sámúẹ́lì 3:19.

“Sámúẹ́lì Ké Pe Jèhófà”

24. Bí àkókò ti ń lọ, ìpinnu wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe? Kí nìdí tí ìpinnu náà fi jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì?

24 Ṣé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì? Ṣé wọ́n wá di olóòótọ́ èèyàn tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run? Rárá o. Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n pinnu pé àwọn kò fẹ́ kí wòlíì lásán máa ṣe onídàájọ́ àwọn. Wọ́n fẹ́ kí èèyàn máa jọba lórí wọn bíi tàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Jèhófà sọ pé kí Sámúẹ́lì ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ fún wọn. Àmọ́, ó ní láti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ wọn ṣe pọ̀ tó. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ kó yé wọn pé kì í ṣe èèyàn lásán ni wọ́n kọ̀, bí kò ṣe Jèhófà fúnra rẹ̀! Torí náà, ó pe àwọn èèyàn náà jọ sí Gílígálì.

Ìgbàgbọ́ tí Sámúẹ́lì ní mú kó gbàdúrà, Jèhófà sì fi ààrá dá a lóhùn

25, 26. Ní Gílígálì, báwo ni Sámúẹ́lì tó ti darúgbó ṣe wá mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí bí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ Jèhófà ṣe burú jáì tó?

25 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wò ó bíi pé a wà lọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Gílígálì ní àkókò tí ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wà lọ́nà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ tó fẹ́ bá wọn sọ. Ibẹ̀ ni Sámúẹ́lì tó ti darúgbó ti rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí bó ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ láìyingin. Lẹ́yìn náà, Bíbélì sọ pé: “Sámúẹ́lì ké pe Jèhófà.” Ó ní kí Jèhófà jẹ́ kí ààrá sán.—1 Sám. 12:17, 18.

26 Ààrá kẹ̀? Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí! Àmọ́, tá a bá tiẹ̀ rí lára àwọn èèyàn náà tí wọ́n rò pé àlá tí ò lè ṣẹ lọ̀rọ̀ náà tàbí tí wọ́n ń ṣe yẹ̀yẹ́, kò pẹ́ tí ẹnu wọn fi wọhò. Ká tó wí ká tó fọ̀, ojú ọ̀run ti ṣú dẹ̀dẹ̀. Ìjì bẹ̀rẹ̀ sí í jà, ó ń fẹ́ lu àwọn àlìkámà inú pápá. Ààrá sán gààràgà, ó milẹ̀ tìtì, òjò sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Kí ni àwọn èèyàn náà ṣe? “Àwọn ènìyàn náà . . . bẹ̀rù Jèhófà àti Sámúẹ́lì gidigidi.” Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n rí bí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá ṣe burú tó.—1 Sám. 12:18, 19.

27. Kí ni Jèhófà máa ń ṣe fún àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ bíi tí Sámúẹ́lì?

27 Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run Sámúẹ́lì ló mú kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn yẹn gbà pé òótọ́ làwọn ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Sámúẹ́lì ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run rẹ̀ yìí láti ìgbà èwe rẹ̀ títí tó fi darúgbó, Ọlọ́run sì san án lẹ́san rere. Títí di báyìí Jèhófà ò tíì yí pa dà. Ó ṣì máa ń ti àwọn tó bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Sámúẹ́lì lẹ́yìn.

^ ìpínrọ̀ 5 Lára ohun tí ẹ̀jẹ́ àwọn Násírì ò fàyè gbà ni pé kí wọ́n mu ọtí líle tàbí kí wọ́n gé irun orí wọn. Àkókò díẹ̀ ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn fi máa ń wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí, àmọ́ àwọn díẹ̀ bíi Sámúsìnì, Sámúẹ́lì àti Jòhánù Oníbatisí jẹ́ Násírì jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn.

^ ìpínrọ̀ 9 Àgọ́ ìjọsìn yìí jẹ́ ilé onígun mẹ́rin tí wọ́n fi àwọn ọwọ̀n onígi gbé ró. Àmọ́, àwọn ohun èlò tó níye lórí jù lọ láyé ìgbà yẹn ni wọ́n fi kọ́ ọ, irú bí awọ séálì, àwọn aṣọ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ọ̀nà aláràbarà sí àti àwọn igi olówó gọbọi tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà bò. Àárín àgbàlá onígun mẹ́rin ni àgọ́ ìjọsìn náà wà, pẹpẹ ńlá kan tí wọ́n fi ń rúbọ sì wà níbẹ̀. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n kọ́ àwọn yàrá míì tí àwọn àlùfáà á máa lò sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àgọ́ ìjọsìn náà. Ó jọ pé ọ̀kan lára àwọn yàrá yẹn ni Sámúẹ́lì ń sùn.

^ ìpínrọ̀ 12 Ìtàn yìí sọ méjì lára irú ìwà àìlọ́wọ̀ bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́ ni pé, Òfin sọ àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n fún àwọn àlùfáà láti jẹ lára ọrẹ ẹbọ. (Diu. 18:3) Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà burúkú tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó yàtọ̀. Ńṣe ni wọ́n máa ń sọ fún àwọn ìránṣẹ́ wọn pé kí wọ́n ki àmúga bọ ẹran tó ń hó lọ́wọ́ nínú ìkòkò, kí wọ́n sì mú èyí tó dára jù lọ nínú àwọn ẹran tó bá gbé jáde! Èkejì ni pé, nígbà táwọn èèyàn bá mú ẹbọ tí wọ́n fẹ́ sun wá síbi pẹpẹ, àwọn àlùfáà burúkú náà á ní kí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ fi tipátipá gba ẹran tútù lọ́wọ́ ẹni tó wá rúbọ, kó tiẹ̀ tó di pé wọ́n fi ọ̀rá ẹran náà rúbọ sí Jèhófà.—Léf. 3:3-5; 1 Sám. 2:13-17.