Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Ooru Ṣe Ń Mú Gan-an Kárí Ayé?
Ní July 2022, ìròyìn tó jáde kárí ayé fi hàn pé oṣù yẹn ni ooru tíì mú jù lọ:
“Lẹ́ẹ̀kejì lóṣù yìí, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Ṣáínà kìlọ̀ pé ooru máa mú gan-an láwọn ìlú tó tó nǹkan bí àádọ́rin (70) lórílẹ̀-èdè náà.”—July 25, 2022, CNN Wire Service.
“Iná ńlá ń sọ láwọn igbó tó wà láwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù torí ojú ọjọ́ tó móoru gan-an.”—July 17, 2022, The Guardian.
“Lọ́jọ́ Sunday, ọ̀pọ̀ ìlú tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni ojú ọjọ́ ti gbóná ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, ìyẹn sì jẹ́ kí ooru mú gan-an káàkiri apá gúúsù àti àárín ìwọ̀ oòrùn títí dé etíkun tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà.”—July 24, 2022, The New York Times.
Kí láwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí túmọ̀ sí? Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí ayé yìí ò ní ṣeé gbé mọ́? Kí ni Bíbélì sọ?
Ṣé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ojú ọjọ́ á máa móoru gan-an?
Bẹ́ẹ̀ ni. Bí ojú ọjọ́ ṣe ń móoru bá àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa àkókò wa yìí mu. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa rí “àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù” tàbí “ohun ẹ̀rù.” (Lúùkù 21:11; Bíbélì Mímọ́) Ojú ọjọ́ tó ń móoru yìí ti mú káwọn kan máa bẹ̀rù pé tó bá yá àwa èèyàn máa ba ayé yìí jẹ́ débi pé kò ní ṣeé gbé mọ́.
Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí ayé yìí ò ní ṣeé gbé mọ́?
Rárá o. Ọlọ́run dá ayé yìí káwa èèyàn lè máa gbé inú ẹ̀ títí láé. (Sáàmù 115:16; Oníwàásù 1:4) Kò ní jẹ́ káwọn èèyàn ba ayé yìí jẹ́, dípò bẹ́ẹ̀ ó ṣèlérí pé òun máa “run àwọn tó ń run ayé.”—Ìfihàn 11:18.
Ẹ jẹ́ ká wo àsọtẹ́lẹ̀ méjì tó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan míì tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe:
“Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀, aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.” (Àìsáyà 35:1) Ọlọ́run ò ní jẹ́ kí ayé yìí di aṣálẹ̀ tí ò ṣeé gbé, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa tún gbogbo ibi tó ti bà jẹ́ ṣe.
“Ò ń bójú tó ayé, o mú kí ó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èso, kí ilẹ̀ rẹ̀ sì lọ́ràá dáadáa.” (Sáàmù 65:9) Lọ́lá ìbùkún Ọlọ́run, gbogbo ayé máa di Párádísè.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà ṣe bá àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mu, ka àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ojú Ọjọ́ Tó Ń Yí Pa Dà àti Ọjọ́ Ọ̀la Wa.”
Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bá a ṣe máa tún ayé yìí ṣe, ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ló Máa Tún Ayé Yìí Ṣe?”