Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ìgbà Wo Ni Gbogbo Ogun Yìí Máa Dópin?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Nígbà tí António Guterres tó jẹ́ Akọ̀wé Àgbà Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn bọ́ǹbù tí orílẹ̀-èdè Iran jù sí orílẹ̀-èdè Israel lọ́jọ́ Saturday, April 13, 2024, ó sọ pé: “Àkókò yìí gan-an ló yẹ ká kó ara wa níjàánu, ká sì dá gbogbo wàhálà yìí dúró.”
Ogun tí wọ́n ń jà lágbègbè Israel kàn jẹ́ ọ̀kan lára ogun tí wọ́n ń jà kárí ayé.
“Látìgbà tí ogun Àgbáyé Kejì ti parí, àsìkò yìí ni ogun tí wọn ń jà karí ayé tíì pọ̀ jù. Àwọn bílíọ̀nù méjì ìyẹn ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn èèyàn tó wà kárí ayé ló ń jìyà nítorí àwọn ogun náà.”—Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí Sọ̀rọ̀ Ààbò ní Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé, January 26, 2023.
Lára àwọn agbègbè tí wọ́n ti ń jà ni Israel, Gaza, Syria, Azerbaijan, Ukraine, Sudan, Ethiopia, Niger, Myanmar, àti Haiti. a
Ìgbà wo ni gbogbo ogun yìí máa dáwọ́ dúró? Ṣé àwọn tó ń ṣàkóso ayé lè mú kí àlàáfíà wà? Kí ni Bíbélì sọ?
Ogun ń jà kárí ayé
Ogun tó ń jà kárí ayé lónìí fi hàn pé láìpẹ́ ogun máa kásẹ̀ nílẹ̀. Àwọn ogun tó ń jà yìí jẹ́ ká rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa àkókò wa ti ń ṣẹ. Bíbélì pe àkókò wa yìí ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 24:3.
“Ẹ máa gbọ́ nípa àwọn ogun, ẹ sì máa gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun. . . . Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.”—Mátíù 24:6, 7.
Tó o bá fẹ́ mọ bí àwọn ogun tó ń jà lónìí ṣe fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń ṣẹ, ka àpilẹ̀kọ “Àwọn Àmì Wo Ló Fi Hàn Pé A Ti Wà Ní ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,’ Tàbí ‘Òpin Ayé’?”
Ogun tó máa fòpin sí gbogbo ogun
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ogun tó ń jà máa tó kásẹ̀ nílẹ̀. Báwo nìyẹn ṣe máa ṣẹlẹ̀? Kì í ṣe àwa èèyàn ló máa mú kíyẹn ṣeé ṣe, dípò bẹ́ẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Amágẹ́dọ́nì tó jẹ́ “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” ni Ọlọ́run máa lò. (Ìfihàn 16:14, 16) Lẹ́yìn ogun yìí, Ọlọ́run máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé aráyé máa gbádùn àlàáfíà tó máa wà pẹ́ títí.—Sáàmù 37:10, 11, 29.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ogun tí Ọlọ́run máa fi fòpin sí gbogbo ogun, ka àpilẹ̀kọ “Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?”
a Ìwádìí nípa ogun látọwọ́ àjọ ACLED , “Bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ogun tó ń jà kárí ayé ṣe burú tó,” January 2024