Ṣé Ó Yẹ Káwọn Ẹlẹ́sìn Lọ́wọ́ sí Òṣèlú?
Kárí ayé, ọ̀pọ̀ àwọn tó pe ara wọn ní ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló máa ń lọ́wọ́ sí òṣèlú. Àwọn kan máa ń dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kan tàbí kí wọ́n ṣàgbátẹrù olóṣèlú kan torí kí wọ́n lè fìdí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tàbí ohun tí wọ́n kà sí ìwà tó bójú mu múlẹ̀. Àwọn olóṣèlú náà á wá gùn lé ìwà táwọn èèyàn ń hù láwùjọ tàbí ọ̀rọ̀ wọn láti sọ àwọn ẹlẹ́sìn di ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú wọn. Kì í ṣe ohun tuntun mọ́ pé káwọn olórí ẹ̀sìn gbé àpótí ìbò torí àti dé ipò òṣèlú. Àwọn orílẹ̀-èdè kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé ẹ̀sìn “Kristẹni” ni wọ́n fi ṣe ẹ̀sìn ìlú.
Kí lèrò rẹ? Ṣé ó yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi máa lọ́wọ́ sí òṣèlú? O lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí tó o bá gbé àpẹẹrẹ Jésù yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.” (Jòhánù 13:15) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Ṣé Jésù lọ́wọ́ sí òṣèlú?
Rárá. Jésù ò lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú.
Jésù ò wá bó ṣe máa di olóṣèlú. Ó kọ̀ láti di alákòóso ìjọba èèyàn nígbà tí Sátánì Èṣù fi “gbogbo ìjọba ayé” lọ̀ ọ́. (Mátíù 4:8-10) a Ìgbà kan tún wà tí àwọn tó mọ̀ pé Jésù máa jẹ́ aṣáájú rere fẹ́ fipá mú kó di olóṣèlú. Bíbélì sọ pé: “Jésù mọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun láti fi òun jẹ ọba, torí náà, ó tún kúrò níbẹ̀, ó sì lọ sórí òkè ní òun nìkan.” (Jòhánù 6:15) Jésù ò ṣe ohun táwọn èèyàn fẹ́ kó ṣe. Ṣe ló kọ̀ láti lọ́wọ́ sí òṣèlú.
Jésù ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn Júù kì í fẹ́ sanwó orí fún ìjọba Róòmù wọ́n sì ka sísan owó orí sí ìnira àti ìrẹ́jẹ. Nígbà tí wọ́n gbìyànjú láti mú kí Jésù bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ náà, kò bá wọn ṣàròyé bóyá ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti sanwó orí. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì, àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Máàkù 12:13-17) Kò dá sọ́rọ̀ náà, kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ kó yé wọn pé ó yẹ kí wọ́n san owó orí tí ìjọba ìlú Róòmù tó ń ṣojú fún Késárì béèrè lọ́wọ́ wọn. Lọ́wọ́ kejì, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ohun tí àwọn aláṣẹ bá sọ pé kí wọ́n ṣe ló yẹ kí wọ́n ṣe. Kò yẹ kéèyàn fún ìjọba èèyàn làwọn nǹkan tó tọ́ sí Ọlọ́run, bí ìfọkànsìn àti ìjọsìn.—Mátíù 4:10; 22:37, 38.
Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù fara mọ́. (Lúùkù 4:43) Kò lọ́wọ́ sí òṣèlú torí ó mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa tún ayé ṣe kì í ṣe ìjọba èèyàn. (Mátíù 6:10) Ó mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ò ní lo èèyàn láti ṣàkóso, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa mú ìjọba èèyàn kúrò pátápátá.—Dáníẹ́lì 2:44.
Ṣé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ́wọ́ sí òṣèlú?
Rárá o. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe “jẹ́ apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19) Wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀, àwọn náà ò sì lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. (Jòhánù 17:16; 18:36) Dípò kí wọ́n lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni tí Jésù pa láṣẹ ni wọ́n gbájú mọ́.—Mátíù 28:18-20; Ìṣe 10:42.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gbà pé ìgbọràn sí Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù, wọ́n tún mọ̀ pé ó yẹ káwọn bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ. (Ìṣe 5:29; 1 Pétérù 2:13, 17) Wọ́n pa òfin mọ́, wọ́n sì sanwó orí. (Róòmù 13:1, 7) Bí wọn ò tiẹ̀ lọ́wọ́ sí òṣèlú, wọ́n máa ń fi òfin dáàbò bo ara wọn, wọ́n sì tún ń jàǹfààní àwọn nǹkan míì tí ìjọba pèsè.—Ìṣe 25:10, 11; Fílípì 1:7.
Àwọn Kristẹni òde òní kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú
Bíbélì fi hàn kedere pé Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ò lọ́wọ́ sí òṣèlú. Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi gbogbo láyé kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” tí Jésù pa láṣẹ ni wọ́n ń ṣe.—Mátíù 24:14.
a Nígbà tí Jésù kọ ìjọba ayé, kò bá Sátánì jiyàn pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fi lọ òun. Nígbà tó yá, ó pe Sátánì ní “alákòóso ayé.”—Jòhánù 14:30