Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìṣòro Omi Tó Kárí Ayé?
Gbogbo wa la nílò omi tó mọ́, tó sì ṣeé mu ká lè wà láàyè. António Guterres tó jẹ́ Akọ̀wé Àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé kìlọ̀ pé “láìpẹ́, omi ò ní tó mọ́ torí omi tá a nílò kárí ayé túbọ̀ ń pọ̀ sí i.” Ó tiẹ̀ bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn kárí ayé ni wọn ò rí omi tó mọ́, tó sì ṣeé mu.
Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí omi tó mọ́, tó sì ṣeé mu máa tó gbogbo wa? Àbí ìṣòro omi yìí làá máa bá yí títí lọ? Kí ni Bíbélì sọ?
Àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa bí omi ṣe máa pọ̀
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tá ò ní ní ìṣòro omi mọ́. Kódà, omi tó mọ́, tó sì ṣeé mu máa pọ̀ yanturu.
“Omi máa tú jáde ní aginjù, odò sì máa ṣàn ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú. Ilẹ̀ tí ooru ti mú kó gbẹ táútáú máa di adágún omi tí esùsú kún inú rẹ̀, ilẹ̀ gbígbẹ sì máa di ìsun omi.”—Àìsáyà 35:6, 7.
Kí nìdí tó fi yẹ ká gba ìlérí inú Bíbélì yìí gbọ́? Ẹ jẹ́ ká wo ohun kan tí Bíbélì sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá ayé wa yìí.
Ohun tí Bíbélì sọ nípa ayé àti bí omi ṣe ń yípo nínú rẹ̀
‘Ọlọ́run ò kàn dá ayé lásán, àmọ́ ó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀.’—Àìsáyà 45:18.
Torí pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé inú ayé títí lọ, ó dá ayé lọ́nà tó fi jẹ́ pé àá máa ní ọ̀pọ̀ yanturu omi tó mọ́, tó sì ṣeé mu.
“[Ọlọ́run] ń fa àwọn ẹ̀kán omi sókè; omi inú àwọsánmà rẹ̀ ń di òjò; àwọsánmà wá rọ òjò; ó rọ̀ sórí aráyé.”—Jóòbù 36:27, 28.
Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣàlàyé ọ̀nà àgbàyanu tí Ọlọ́run gbà ṣe é kí omi lè máa yípo, kí omi tó dáa lè máa wà nígbà gbogbo. Oòrùn máa ń fa omi tó wà lórí ilẹ̀ àti nínú òkun lọ sínú òfúrufú. Tó bá yá, á rọ̀ bí òjò, ìyẹn sì máa ń jẹ́ káwa èèyàn àtàwọn ẹranko ní omi tó mọ́ nígbà gbogbo.—Oníwàásù 1:7; Émọ́sì 5:8.
“Èmi yóò rọ ọ̀wààrà òjò fún yín ní àkókò tó yẹ, ilẹ̀ yóò mú èso jáde, àwọn igi oko yóò sì so èso.”—Léfítíkù 26:4.
Ọlọ́run ṣèlérí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ tí ọ̀pọ̀ wọn jẹ́ àgbẹ̀ pé òun máa bù kún wọn ní ti pé òun á jẹ́ kí òjò máa rọ̀ lásìkò tó yẹ. Ọlọ́run mọ̀ pé kí ohun tí wọ́n gbìn tó lè hù dáadáa, òjò gbọ́dọ̀ máa rọ̀ lásìkò tó yẹ.
Ọlọ́run wá ṣèlérí pé láìpẹ́ òun máa ṣe ohun kan náà fún gbogbo ayé. (Àìsáyà 30:23) Ní báyìí náà, ọ̀pọ̀ ibi láyé làwọn èèyàn ti níṣòro omi, òjò tí ò rọ̀ dáadáa nìkan kọ́ ló sì ń fa ìṣòro yìí. Kí wá ni Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe sáwọn nǹkan míì tó ń fa ìṣòro omi láyé?
Bí ìṣòro omi ṣe máa dópin
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti fòpin sáwọn ìṣòro tá à ń bá yí láyé yìí, títí kan ìṣòro omi. (Mátíù 6:9, 10) Àtọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run á ti máa ṣàkóso ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Ìfihàn 11:15) Ìjọba yìí máa ṣe ohun táwọn ìjọba èèyàn ò lè ṣe, ìyẹn kí wọ́n yanjú ohun tó ń fa ìṣòro omi.
Ìṣòro: Ojú ọjọ́ tó ń burú sí i wà lára ohun tí kò jẹ́ kí nǹkan rí bó ṣe yẹ. Bí àpẹẹrẹ, ìṣòro ojú ọjọ́ máa ń fa ọ̀gbẹlẹ̀ láwọn ibì kan, ó sì lè fa àkúnya omi láwọn ibòmíì nítorí àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò tàbí òkun tó ya.
Ojútùú: Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí ojú ọjọ́ pa dà sí bó ṣe yẹ kó wà, ìyẹn sì máa mú kí ayé pa dà sí bó yẹ ṣe kó rí. Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” (Ìfihàn 21:5) Ọlọ́run máa mú kí omi pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ tó gbẹ táútáú, ìyẹn á sì mú káwọn ibi tó dà bíi pé kò ṣeé gbé sọjí pa dà. (Àìsáyà 41:17-20) Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí ojú ọjọ́ rí bó ṣe yẹ, àjálù ò sì ní máa ṣẹlẹ̀ mọ́.
Nígbà tí Jésù wà láyé, ó dá ìjì alágbára kan dúró, ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run ti fún un lágbára lórí àwọn ohun àdáyébá. (Máàkù 4:39, 41) Kò sí àní-àní pé lábẹ́ àkóso Jésù Ọba Ìjọba Ọlọ́run, àjálù ò ní ṣẹlẹ̀ mọ́. Ọkàn gbogbo èèyàn á balẹ̀, a ò sì ní máa bẹ̀rù àjálù èyíkéyìí mọ́.
Ìṣòro: Àwọn olójúkòkòrò àtàwọn iléeṣẹ́ oníjẹkújẹ kì í ro tàwọn míì mọ́ tiwọn. Wọ́n sì máa ń da àwọn ìdọ̀tí burúkú sínú odò, sínú òkun àti sínú àwọn àgbájọ omi tó wà lábẹ́ ilẹ̀, ìyẹn sì wà lára ohun tó ń fa ìṣòro omi láyé.
Ojútùú: Ọlọ́run máa fọ ayé mọ́, ó sì máa mú káwọn odò, òkun àti ilẹ̀ pa dà sí bó ṣe yẹ kó wà. Ayé á wá di Párádísè. Bíbélì tiẹ̀ sọ lọ́nà ewì pé: “Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀, aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.”—Àìsáyà 35:1.
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó jẹ́ olójúkòkòrò àti oníjẹkújẹ tí ò ro tàwọn míì mọ́ tiwọn? Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa “pa àwọn tó ń pa ayé run.”—Ìfihàn 11:18, àlàyé ìsàlẹ̀; Òwe 2:21, 22.
Ìṣòro: Àwọn èèyàn máa ń lo omi tó wà nílòkulò, ìyẹn sì ń mú kí ìwọ̀nba omi tó ṣẹ́ kù dín kù sí i.
Ojútùú: Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí “ìfẹ́ [Ọlọ́run] ṣẹ ní ayé” dípò ìfẹ́ àwọn èèyàn tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀. (Mátíù 6:9, 10) Ìjọba Ọlọ́run tún máa kọ́ àwọn èèyàn láwọn ìwà rere tó yẹ kí wọ́n ní. Àìsáyà 11:9 sọ pé: “Ó dájú pé ìmọ̀ Jèhófà máa bo ayé.” a Táwa èèyàn bá ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí, tá a sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti gbogbo ohun tó dá, ó dájú pé àá lè bójú tó ayé yìí àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ dáadáa.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?”
Ka Àìsáyà orí 35, kíwọ fúnra rẹ lè rí bí Ọlọ́run ṣe máa sọ ayé yìí di Párádísè.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé àtàwa èèyàn, wo fídíò náà Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé?
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”