ÀKÀNṢE ÌWÀÁSÙ
Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Ogun
Ogun tó ń jà kárí ayé ti ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́, ó sì ti fa ọ̀pọ̀ ìnira fáwọn èèyàn. Kíyè sí àwọn ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí:
“Iye àwọn tí ogun pa lórílẹ̀-èdè Etiópíà àti Ukraine lọ́dún tó kọjá nìkan ju àwọn tí ogun ti pa láti 1994.” —Peace Research Institute Oslo, June 7, 2023.
“Lọ́dún 2022, ogun tó jà ní Ukraine wà lára ogun tó tíì burú jù lọ. Kárí ayé ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn olóṣèlú légbá kan sí i lọ́dún tó kọjá, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lèyí sì ṣàkóbá fún.”—The Armed Conflict Location & Event Data Project (ACLED), February 8, 2023.
Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀. Ó sọ pé “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ Ìjọba yìí, Ọlọ́run máa “fòpin sí ogun kárí ayé.”—Sáàmù 46:9.