Ta Ló Máa Tún Ayé Yìí Ṣe?
Inú ọ̀pọ̀ ò dùn torí báwọn èèyàn ṣe ń ba ayé yìí jẹ́ àti bí wọ́n ṣe ń ṣèpalára fáwọn ẹ̀dá alààyè tó wà nínú rẹ̀. Àwọn onímọ̀ nípa àyíká sọ pé àwọn nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe lónìí lè mú kí onírúurú ẹ̀dá alààyè pòórá pátápátá láyé, ó sì ń ṣèpalára fún àyíká àtàwọn ẹranko ju ti ìgbàkígbà rí lọ.
Ṣé àwọn èèyàn máa pa ayé yìí run? Àbí wọ́n á lè máa ṣe nǹkan lọ́nà tí wọn ò fi ní ba àwọn ohun tó wà láyé jẹ́?
Ṣé àwọn èèyàn máa lè tún ayé yìí ṣe?
Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé gbà pé àwọn èèyàn máa lè tún ayé yìí ṣe. Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé káwọn èèyàn tó lè tún ayé yìí ṣe, àwọn ìyípadà kan gbọ́dọ̀ wáyé, àwọn ìyípadà náà sì gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Lára àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ ni:
Káwọn èèyàn túbọ̀ máa fọwọ́ pàtàkì mú bí wọ́n ṣe ń bójú tó ilẹ̀, igbó, àwọn ilẹ̀ olómi àti òkun.
Kí wọ́n máa ṣọ̀gbìn kí wọ́n sì máa pèsè ohun àmúṣagbára lónírúurú ọ̀nà.
Kí ìyípadà dé bá ìpèsè oúnjẹ àti bó ṣe ń dé ọ̀dọ̀ aráàlú káwọn èèyàn lè máa jẹ ohun tó ń wá látara ewéko pẹ̀lú ẹran àti ẹja tó mọ níwọ̀n, kí wọ́n má jẹ àjẹjù kí wọ́n má sì fi oúnjẹ ṣòfò.
Kí wọ́n gbà pé kíkó ohun ìní tara jọ ṣáá kọ́ ló ń mú kéèyàn gbé ìgbé ayé tó dáa.
Kí lèrò rẹ? Ṣó yẹ ká ronú pé ìjọba, àwọn ilé iṣẹ́ àtàwọn èèyàn máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti mú kí nǹkan túbọ̀ dáa? Àbí o rò pé kò ní lè ṣeé ṣe torí olójúkòkòrò, onímọtara-ẹni-nìkan àti ẹni tí kìí ronú nípa ọjọ́ iwájú lọ̀pọ̀ lára wọn?—2 Tímótì 3:1-5.
Ìdí tá a fi ní ìrètí
Bíbélì fi dá wa lójú pé ayé yìí ò ní parun. Ó ṣàlàyé ìdí táwọn èèyàn ò fi ní lè tún ayé yìí ṣe, ó sì jẹ́ ká mọ ìjọba tó máa tún ayé yìí ṣe àti bí àyípadà náà ṣe máa wáyé.
Ìdí táwọn èèyàn ò fi ní lè tún ayé ṣe. Jèhófà a Ọlọ́run ló dá ayé, ó sì ní kí àwọn èèyàn máa bójú tó o. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15) Kí wọ́n tó lè ṣàṣeyọrí, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ọlọ́run máa tọ́ wọn sọ́nà, kí wọ́n sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. (Òwe 20:24) Àmọ́ dípò tí wọ́n máa fi ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n kọ Jèhófà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dá tara wọn ṣe. (Oníwàásù 7:29) Àwọn èèyàn ò lágbára láti tún ayé yìí ṣe, kò sí bí wọ́n ṣe lè sapá tó, pàbó náà ni gbogbo ẹ̀ máa já sí.—Òwe 21:30; Jeremáyà 10:23.
Ohun tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀. Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn tó ń ba ayé jẹ́ run. (Ìfihàn 11:18) Kò ní bá ìjọba àtàwọn èèyàn tó ń pa ayé run tún ayé ṣe; ṣe ló máa fi ìjọba míì rọ́pò tiwọn. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ pé: “Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.”—Ìfihàn 21:5.
Bí ìyípadà náà ṣe máa wáyé. Jèhófà máa fi ìjọba rẹ̀ rọ́pọ̀ ìjọba èèyàn. Jésù Kristi ló máa jẹ́ ọba ìjọba náà, ó sì máa ṣàkóso ayé.—Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10.
Ìjọba Ọlọ́run máa kọ́ àwọn èèyàn ní ìlànà òdodo Ọlọ́run kí wọ́n lè máa fi ṣèwà hù. Táwọn èèyàn bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà, wọ́n á máa ṣe nǹkan lọ́nà tí wọn ò fi ní ba àwọn ohun tó wà láyé jẹ́. (Àìsáyà 11:9) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run àwọn èèyàn máa gbádùn ìgbésí ayé tó dáa, ẹnikẹ́ni ò sì ní ba ayé jẹ́. Àwọn ohun tá a máa gbádùn rèé:
Oúnjẹ á wà fún gbogbo èèyàn.—Sáàmù 72:16.
Àwọn ohun àdáyébá á padà bọ̀ sípò.—Àìsáyà 35:1, 2, 6, 7.
Àlàáfíà máa wà láàárín àwọn èèyàn àti ẹranko.—Àìsáyà 11:6-8; Hósíà 2:18.
Á fòpin sí àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká.—Máàkù 4:37-41.
Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó ṣe àwọn ìyípadà yìí. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?”
a Jèhófa ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.