ORIN 141
Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́
-
1. Ọmọ jòjòló, ọ̀wààrà òjò,
Ìmọ́lẹ̀ oòrùn àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ;
Gbogbo wọn ló jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run.
Wọ́n jẹ́rìí síṣẹ́ ìyanu ojoojúmọ́.
(ÈGBÈ)
Ẹ̀bùn yìí ṣọ̀wọ́n ó sì ṣeyebíye.
Báwo la ṣe lè fi hàn pá a mọyì ẹ̀bùn yìí?
Ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká fìmọrírì hàn;
Ẹ̀bùn ìyanu ńlá ni ìwàláàyè jẹ́.
-
2. Àwa kò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ láé,
Bíi taya Jóòbù tó sọ fọ́kọ rẹ̀ pé:
‘Bú Ọlọ́run rẹ, ṣe tán láti kú.’
Àwa yóò máa yin Ọlọ́run wa títí láé.
(ÈGBÈ)
Ẹ̀bùn yìí ṣọ̀wọ́n ó sì ṣeyebíye.
Báwo la ṣe lè fi hàn pá a mọyì ẹ̀bùn yìí?
Ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká fìmọrírì hàn;
Ẹ̀bùn ìyanu ńlá ni ìwàláàyè jẹ́.
(Tún wo Jóòbù 2:9; Sm. 34:12; Oníw. 8:15; Mát. 22:37-40; Róòmù 6:23.)