ORIN 156
Mo Ní Ìgbàgbọ́
1. Ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀
Bí ọ̀tá tilẹ̀ ń gbógun.
Jèhófà wà lẹ́yìn mi,
Èmi kò ní bẹ̀rù.
Atófaratì ni Baba.
(ÈGBÈ)
Ó dá mi lójú pé
ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.
Kò sí ìbẹ̀rù kankan
lọ́rọ̀ mi.
Jèhófà Ọlọ́run ni
Alátìlẹ́yìn mi.
Mo mọ̀ pé
kò ní já mi kulẹ̀;
Mo nígbàgbọ́.
2. Àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà
Tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn;
Wọ́n máa gba èrè wọn
Torí ìgbàgbọ́ wọn.
Jèhófà máa jí wọn dìde.
(ÈGBÈ)
Ó dá mi lójú pé
ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.
Kò sí ìbẹ̀rù kankan
lọ́rọ̀ mi.
Jèhófà Ọlọ́run ni
Alátìlẹ́yìn mi.
Mo mọ̀ pé
kò ní já mi kulẹ̀;
Mo nígbàgbọ́.
(ÀSOPỌ̀)
Ìgbàgbọ́ ló
jẹ́ kí n ṣọkàn akin.
Mo nírètí
tó dájú gan-an.
Ìgbàgbọ́ mi
Ló jẹ́ kí n máa
fara dà á lọ
Bí ìṣòro tilẹ̀ pọ̀ gan-an.
3. Jèhófà ló ṣèlérí
Pé ayé tuntun ń bọ̀.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.
Jèhófà kì í parọ́.
Baba, jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́ dópin.
(ÈGBÈ)
Ó dá mi lójú pé
ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.
Kò sí ìbẹ̀rù kankan
lọ́rọ̀ mi.
Jèhófà Ọlọ́run ni
Alátìlẹ́yìn mi.
Mo mọ̀ pé
kò ní já mi kulẹ̀;
Mo nígbàgbọ́.
Mo nígbàgbọ́.
(Tún wo Héb. 11:1-40.)