ORIN 57
Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn
-
1. A fẹ́ fi ìwà jọ Ọlọ́run wa,
Torí Jèhófà kì í ṣojúsàájú.
Gbogbo onírúurú èèyàn ló ń pè,
Kí wọ́n dọ̀rẹ́ rẹ̀, kó lè gbà wọ́n là.
(ÈGBÈ)
Ibi yòówù kí wọ́n wà,
Ọkàn ló ṣe pàtàkì.
Onírúurú àwọn èèyàn là ńwá.
Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ
Wàásù ní ibi gbogbo
Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
-
2. Ibi yòówù kí a ti lè rí wọn,
Bí wọ́n ṣe rí kọ́ ló ṣe pàtàkì.
Ṣùgbọ́n bí inú ọkàn wọn ṣe rí
Ló ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà.
(ÈGBÈ)
Ibi yòówù kí wọ́n wà,
Ọkàn ló ṣe pàtàkì.
Onírúurú àwọn èèyàn là ńwá.
Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ
Wàásù ní ibi gbogbo
Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
-
3. Gbogbo àwọn tó ti ṣe ìpinnu
Láti fàwọn ìwà ayé sílẹ̀,
La mọ̀ pé Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà,
À ń lọ wàásù kí aráyé lè mọ̀.
(ÈGBÈ)
Ibi yòówù kí wọ́n wà,
Ọkàn ló ṣe pàtàkì.
Onírúurú àwọn èèyàn là ńwá.
Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ
Wàásù ní ibi gbogbo
Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
(Tún wo Jòh. 12:32; Ìṣe 10:34; 1 Tím. 4:10; Títù 2:11.)