ORIN 64
À Ń Fayọ̀ Ṣe Iṣẹ́ Ìkórè Náà
-
1. Àǹfààní àláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́
Pé ìgbà ‘kórè la wà yìí.
Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀, ká bọ́ sí pápá,
Ká sì sa gbogbo ipá wa.
Torí pé Kristi wà pẹ̀lú wa,
Tó ń darí iṣẹ́ tá à ń ṣe yìí,
Èyí ń fún wa láyọ̀ lójoojúmọ́,
Ọlá ńlá ló sì jẹ́ fún wa.
-
2. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
Àtàwọn aládùúgbò wa,
Ó ń mú ká tẹra mọ́ ìwàásù,
Torí òpin ti sún mọ́lé.
À ń láyọ̀ bí a ṣe ńṣiṣẹ́ yìí;
Jèhófà ló ń fún wa láyọ̀.
A ó fìgbàgbọ́ fara dà á dé òpin,
A ó sì máa fayọ̀ bá a ṣiṣẹ́.
(Tún wo Mát. 24:13; 1 Kọ́r. 3:9; 2 Tím. 4:2.)