ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Fílípì 4:13—“Mo Lè Ṣe Ohun Gbogbo Nínú Kristi”
“Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”—Fílípì 4:13, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Mo lè ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni tí ó ń fún mi ní agbára.”—Fílípì 4:13, Bíbélì Mímọ́.
Ìtumọ̀ Fílípì 4:13
Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yìí jẹ́ kó dá àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lójú pé Ọlọ́run máa fún wọn lágbára láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan sọ pé Kristi ló fún Pọ́ọ̀lù lágbára. Àmọ́, ọ̀rọ̀ náà “Kristi” kò sí nínú àwọn Ìwé Mímọ́ Gíríìkì àfọwọ́kọ tó pẹ́ jù lọ. Torí náà, nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì òde òní, wọ́n lo ọ̀rọ̀ bí “ẹni tó ń fún mi lágbára” (Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun), “ẹniti nfi agbara fun mi” (Bíbélì Mímọ́) àti “ẹni tó jẹ́ orísun àgbára mi” (Bíbélì New American Bible). Torí náà, ta ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí?
Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ ṣáájú nínú lẹ́tà rẹ̀ yìí fi hàn pé Ọlọ́run ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí. (Fílípì 4:6, 7, 10) Pọ́ọ̀lù ti kọ́kọ́ sọ nínú lẹ́tà kan náà tó kọ sí àwọn ará Fílípì pé: “Ọlọ́run ni ẹni tó ń fún yín lágbára . . . ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.” (Fílípì 2:13) Bákan náà, Pọ́ọ̀lù sọ ní 2 Kọ́ríńtì 4:7, pé Ọlọ́run ló fún òun lágbára láti parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun. (Fi wé 2 Tímótì 1:8.) Torí náà, a ní ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí bó ṣe sọ pé “ẹni tó ń fún mi lágbára.”
Kí ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ní okun láti ṣe “ohun gbogbo” túmọ̀ sí? Ó dájú pé onírúurú ìṣòro tí Pọọlù kojú torí kó lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Ọlọ́run máa bójú tó òun bóyá àwọn nǹkan tara díẹ̀ lòún ní tàbí púpọ̀. Ó wá kọ́ béèyàn ṣe ń ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ipò èyíkéyìí tó bá wà.—2 Kọ́ríńtì 11:23-27; Fílípì 4:11.
Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí lè fi àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lóde òní lọ́kàn balẹ̀. Ọlọ́run máa fún wọn ní okun tí wọ́n nílò kí wọ́n lè fara da àwọn ìṣòro, kí wọ́n sì lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ọlọ́run lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tàbí agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀ láti fún wọn lókun, ó sì tún máa ń lo àwọn tá a jọ ń jọ́sìn Ọlọ́run àti Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Lúùkù 11:13; Ìṣe 14:21, 22; Hébérù 4:12.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Fílípì 4:13
Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ kẹ́yìn nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Fílípì. Ó kọ lẹ́tà yìí ní nǹkan bí ọdún 60 sí 61 Sànmánì Kristẹni, nígbà tó kọ́kọ́ ṣẹ̀wọ̀n ní ìlú Róòmù. Àwọn Kristẹni tó wà nílùú Fílípì ò lè fi àwọn nǹkan tí àpọsítélì Pọ́ọ̀lù nílò ránṣẹ́ sí i fáwọn àkókò kan. Àmọ́, nígbà tó yá, wọ́n fi àwọn nǹkan tó nílò ránṣẹ́ sí i.—Fílípì 4:10, 14.
Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fáwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí wọ́n fi hàn, ò sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ti ní gbogbo ohun tí òun nílò. (Fílípì 4:18) Bákan náà, ó lo àǹfààní yẹn láti sọ àṣírí béèyàn ṣe ń gbé ìgbé ayé tó yẹ Kristẹni fún wọn: Gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ lè ní ojúlówó ayọ̀ tí wọ́n bá gbára lé Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́, bóyá wọ́n ní tàbí wọn kò ní.—Fílípì 4:12.