Kí Ni Bábílónì Ńlá?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bábílónì Ńlá, tí ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe rẹ̀, ni àgbájọ gbogbo ìsìn èké tó wà láyé tí Ọlọ́rùn ò fọwọ́ sí. a (Ìṣípayá 14:8; 17:5; 18:21) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìsìn yìí yàtọ̀ síra lóríṣiríṣi ọ̀nà, gbogbo wọn ló ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà kan tàbí òmíràn kí wọ́n má bàa jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́.—Diutarónómì 4:35.
Àwọn ohun tá a lè fi dá Bábílónì Ńlá mọ̀
Àmì ni Bábílónì Ńlá jẹ́. Bíbélì fi wé “obìnrin” àti “aṣẹ́wó ńlá,” tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ “ohun ìjìnlẹ̀ kan: ‘Bábílónì Ńlá.’” (Ìṣípayá 17:1, 3, 5) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “àmì” ni ìwé Ìṣípayá, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Bábílónì Ńlá kì í ṣe obìnrin gidi, àmì ló jẹ́. (Ìṣípayá 1:1) Bákan náà, ó “jókòó lórí omi púpọ̀,” èyí tó ṣàpẹẹrẹ “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 17:1, 15) Obìnrin gidi kan ò lè ṣe ohun tí Bíbélì sọ yìí.
Bábílónì Ńlá ṣàpẹ̀ẹrẹ àwùjọ kan to nasẹ̀ dé orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Bíbélì pè é ní “ìlú ńlá títóbi tí ó ní ìjọba kan lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 17:18) Torí náà, kárí ayé ni ẹsẹ̀ rẹ̀ ti tólẹ̀.
Ètò ìsìn ni Bábílónì Ńlá, kì í ṣe ètò ìṣèlú tàbí ọrọ̀ ajé. Ìlú Bábílónì ayé àtijọ́ gbóná tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ìlú tí wọ́n ti ń fi “èèdì” di ẹni, tí wọ́n sì ti ń ṣe “iṣẹ́ àjẹ́” làwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí. (Aísáyà 47:1, 12, 13; Jeremáyà 50:1, 2, 38) Kódà, Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ kọ́ ni wọ́n ń jọ́sìn níbẹ̀, ẹ̀sìn èké ni wọ́n ń ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 10:8, 9; 11:2-4, 8) Agbéraga làwọn tó ń ṣàkóso ní Bábílónì, wọ́n ò sì ka Jèhófà àti ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn rẹ̀ sí nǹkan kan. (Aísáyà 14:4, 13, 14; Dáníẹ́lì 5:2-4, 23) Bákan náà, àwọn èèyàn tún mọ Bábílónì Ńlá sí ‘abẹ́mìílò.’ Ìyẹn ló fi hàn lóòótọ́ pé ètò ìsìn ni.—Ìṣípayá 18:23.
Bábílónì Ńlá ò lè jẹ́ ètò ìṣèlú, torí pé “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” máa ṣọ̀fọ̀ nígbà tó bá pa run. (Ìṣípayá 17:1, 2; 18:9) Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ètò ọrọ̀ ajé, torí ohun tí Bíbélì sọ fi hàn pé ó yàtọ̀ sí “àwọn olówò arìnrìn-àjò ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 18:11, 15.
Àpèjúwe tí Bíbélì ṣe nípa ìsìn èké bá Bábílónì Ńlá mu. Ṣe ni ìsìn èké ń mú káwọn èèyàn máa jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì dípò kó máa kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Bíbélì pe ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ní “àgbèrè” ẹ̀sìn. (Léfítíkù 20:6, Bíbélì Mímọ́; Ẹ́kísódù 34:15, 16) Ìlú Bábílónì ayé àtijọ́ ni àwọn ẹ̀kọ́ bíi Mẹ́talọ́kan àti àìleèkú ọkàn ti wá, títí kan àṣà fífi ère jọ́sìn. Àwọn àṣà àti ẹ̀kọ́ yẹn ò kúrò lọ́wọ́ ìsìn èké títí dòní. Àwọn ẹ̀sìn yìí tún ń ṣèyí-ṣọ̀hún, wọ́n láwọn ń jọ́sìn, wọ́n tún ń nífẹ̀ẹ́ ayé. Ìwà àìṣòótọ́ nìyẹn, Bíbélì sì fi wọ́n wé àwọn tó ń ṣe panṣágà.—Jákọ́bù 4:4.
Bíbélì fi Bábílónì Ńlá wé obìnrin tó wọ “aṣọ aláwọ̀ àlùkò àti rírẹ̀dòdò,” wọ́n sì “fi wúrà àti òkúta ṣíṣeyebíye àti àwọn péálì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.” Àfiwé yìí bá ìsìn èké mu torí ó lọ́rọ̀, ó sì fi ń yangàn. (Ìṣípayá 17:4) Bábílónì Ńlá ni orísun “àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé” tàbí àwọn ẹ̀kọ́ àti ìwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí. (Ìṣípayá 17:5) Àwọn tó wà nínú ìsìn èké ni “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n” tó ń ti Bábílónì Ńlá lẹ́yìn.—Ìṣípayá 17:15.
Bábílónì Ńlá ló fa ikú “gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 18:24) Ọjọ́ pẹ́ tí ìsìn èké ti ń rúná sí ogun, tí wọ́n sì ń kọ́wọ́ ti àwọn apániláyà, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò fi òtítọ́ nípa Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́ kọ́ àwọn èèyàn. (1 Jòhánù 4:8) Ohun tí wọ́n ṣe yìí ti mú kí ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ sí i. Torí náà, àwọn tó fẹ́ ṣèfẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ “jáde kúrò nínú rẹ̀,” ìyẹn ni pé kí wọ́n kúrò nínú ìsìn èké, torí ìdí pàtàkì wà tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìṣípayá 18:4; 2 Kọ́ríńtì 6:14-17.
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?”