Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Kò Ní Ìdáríjì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì ni ìwà àti ìṣesí tí kò ní jẹ́ kéèyàn rí ìdáríjì gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Báwo lèèyàn ṣe lè ní irú ìwà bẹ́ẹ̀?
Ọlọ́run máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tí wọ́n ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí wọ́n sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. (Ìṣe 3:19, 20) Àmọ́, ẹnì kan lè jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀ débi pé ìwà burúkú náà àti ìṣesí rẹ̀ kò ní ṣeé yí pa dà mọ́. Bíbélì sọ pé ‘agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ ti sọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ di aláyà líle,’ ọkàn wọn sì ti di “ọkàn-àyà burúkú.” (Hébérù 3:12, 13) Bí ìkòkò amọ̀ tí wọ́n ti sun, tí kò ṣeé fi mọ nǹkan míì, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe yigbì, kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn mọ́. (Aísáyà 45:9) Kò sí ìdí kankan tó máa mú kí Ọlọ́run dárí ji irú ẹni bẹ́ẹ̀. Torí náà, ẹ̀ṣẹ̀ ẹni yẹn ti burú débi pé kò lè rí ìdáríjì gbà mọ́.—Hébérù 10:26, 27.
Nígbà ayé Jésù, àwọn kan nínú àwọn aṣáájú ìsìn Júù dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Wọ́n mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló ran Jésù lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìyanu, síbẹ̀ ẹ̀tanú mú kí wọ́n sọ pé ọ̀dọ̀ Sátánì Èṣù ni Jésù ti rí agbára rẹ̀.—Máàkù 3:22, 28-30.
Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọ́run lè dárí rẹ̀ jini
Ọ̀rọ̀ òdì téèyàn sọ torí àìmọ̀kan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti fìgbà kan rí jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì, àmọ́ ó sọ pé: “A fi àánú hàn sí mi, nítorí tí mo jẹ́ aláìmọ̀kan, tí mo sì gbé ìgbésẹ̀ nínú àìnígbàgbọ́.”—1 Tímótì 1:13.
Panṣágà. Bíbélì sọ nípa àwọn tó ṣe panṣágà rí, àmọ́ tí wọ́n yíwà pa dà, tí Ọlọ́run sì dárí jì wọ́n.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
“Ṣé mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì?”
Tó o bá kábàámọ̀ àwọn ìwà burúkú tó o ti hù sẹ́yìn, tó o sì fẹ́ yí pa dà, á jẹ́ pé o kò tíì dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Tó o bá tiẹ̀ ń ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ kan náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, Ọlọ́run ṣì lè dárí jì ẹ́ tó o bá ṣì ní ìbẹ̀rù rẹ̀ lọ́kàn.—Àìsáyà 1:18.
Àwọn kan máa ń rò pé àwọn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì torí pé ọkàn wọn ṣì máa ń dá wọn lẹ́bi. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọkàn wa lè tàn wá nígbà míì. (Jeremáyà 17:9) Ọlọ́run kò fún wa lẹ́tọ̀ọ́ láti dá ara wa tàbí ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́. (Róòmù 14:4, 12) Torí náà, Ọlọ́run lè dárí jì wá tí ọkàn wa bá tiẹ̀ ń dá wa lẹ́bi.—1 Jòhánù 3:19, 20.
Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì ni Júdásì Ísíkáríótù dá?
Bẹ́ẹ̀ ni. Ìwọra mú kó máa jí owó tí wọ́n ṣètò fún iṣẹ́ Ọlọ́run. Ó tiẹ̀ tún díbọ́n bí ẹni tí ọ̀rọ̀ àwọn tálákà jẹ lọ́kàn, àmọ́ bó ṣe máa rí owó jí ló wà lọ́kàn rẹ̀. (Jòhánù 12:4-8) Nígbà tí ọkàn Júdásì wá jingíri sí ìwà burúkú yẹn, ńṣe ló da Jésù torí ọgbọ̀n [30] ẹyọ fàdákà. Jésù mọ̀ pé Júdásì ò lè ronú pìwà dà fún ohun tó ṣe, torí náà ó pè é ní “ọmọ ìparun.” (Jòhánù 17:12) Èyí túmọ̀ sí pé nígbà tí Júdásì kú, ńṣe ló pa run pátápátá, kò sì ní jíǹde lọ́jọ́ iwájú.—Máàkù 14:21.
Júdásì kò ronú pìwà dà látọkàn wá fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kàkà kó jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run, àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n jọ lẹ̀dí àpò pọ̀ ló lọ jẹ́wọ́ fún.—Mátíù 27:3-5; 2 Kọ́ríńtì 7:10.