Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìdá Mẹ́wàá?
Ohun tí Bíbélì sọ
Káwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ lè ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn, Ọlọ́run pàṣẹ pé kí wọ́n máa san ìdá mẹ́wàá a tàbí ìpín kan nínú mẹ́wàá lára ohun tó ń wọlé fún wọn lọ́dọọdún. Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “O gbọ́dọ̀ rí i pé ò ń san ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí irúgbìn rẹ bá ń mú jáde lọ́dọọdún.”—Diutarónómì 14:22.
Òfin ìdá mẹ́wàá wà lára Òfin Mósè, ó wà lára òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́. Àwọn Kristẹni kì í san ìdá mẹ́wàá lónìí torí pé Òfin Mósè kọ́ ló ń darí wọn. (Kólósè 2:13, 14) Dípò ìyẹn, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa ń fi owó ṣètìlẹ́yìn “gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.”—2 Kọ́ríńtì 9:7.
Bí wọ́n ṣe san ìdá mẹ́wàá nínú Bíbélì —“Májẹ̀mú Láéláé”
Léraléra ni wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ìdá mẹ́wàá nínú apá kan Bíbélì táwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Láéláé. Èyí tó pọ̀ jù níbẹ̀ ló jẹ́ ẹ̀yìn tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin (Òfin Mósè) nípasẹ̀ Mósè. Àmọ́, àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n mẹ́nu kàn án kí Ọlọ́run tó fún wọn ní Òfin Mósè.
Ṣáájú Òfin Mósè
Ẹni tó kọ́kọ́ san ìdá mẹ́wàá nínú Bíbélì ni Ábúrámù (Ábúráhámù). (Jẹ́nẹ́sísì 14:18-20; Hébérù 7:4) Ó ṣe kedere pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni Ábúrámù san ìdá mẹ́wàá fún ọba àti àlùfáà ìlú Sálẹ́mù. Kò sí ẹ̀rí kankan nínú Bíbélì tó fi hàn pé Ábúráhámù tàbí àwọn ọmọ ẹ̀ tún san ìdá mẹ́wàá lẹ́yìn ìgbà yẹn.
Ẹnì kejì tí Bíbélì sọ pé ó san ìdá mẹ́wàá ni Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ọmọ Ábúráhámù. Ó ṣèlérí pé tí Ọlọ́run bá bù kún òun, òun máa fún Ọlọ́run ní “ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun” tó bá fún òun. (Jẹ́nẹ́sísì 28:20-22) Àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹran ni Jékọ́bù fi rúbọ kó lè san ìdá mẹ́wàá yìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jékọ́bù mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ torí pé ó san ìdá mẹ́wàá náà, kò fipá mú ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ̀ láti san án.
Lábẹ́ Òfin Mósè
Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé kí wọ́n máa san ìdá mẹ́wàá láti fi ti ìjọsìn wọn lẹ́yìn.
Àwọn ọmọ Léfì àtàwọn àlùfáà tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni wọ́n máa ń san ìdá mẹ́wàá yìí fún torí pé wọn ò ní ilẹ̀ tí wọ́n lè fi dáko. (Nọ́ńbà 18:20, 21) Àmọ́, àwọn ọmọ Léfì tí kì í ṣe àlùfáà máa ń gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì máa ń fún àwọn àlùfáà ní èyí tó dáa jù nínú “ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá” tí wọ́n gbà.—Nọ́ńbà 18:26-29.
Ó jọ pé ìdá mẹ́wàá míì tún wà tí wọ́n máa ń san láàárín ọdún, àwọn ọmọ Léfì àtàwọn tí kì í ṣe ọmọ Léfì ló sì máa ń jàǹfààní nínú ẹ̀. (Diutarónómì 14:22, 23) Ìgbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ayẹyẹ pàtàkì kan làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń san ìdá mẹ́wàá yìí, tó bá sì di àwọn ọdún pàtó kan, wọ́n máa ń fi ìdá mẹ́wàá náà ran àwọn òtòṣì lọ́wọ́.—Diutarónómì 14:28, 29; 26:12.
Báwo ni wọ́n ṣe máa ń ṣírò ìdá mẹ́wàá? Lọ́dọọdún, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ya ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí irúgbìn wọn bá mú jáde sọ́tọ̀. (Léfítíkù 27:30) Tó bá jẹ́ pé wọ́n fẹ́ sọ ìdá mẹ́wàá yìí di owó dípò ohun tí irúgbìn wọn mú jáde, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ìdá márùn-ún iye tí wọ́n fẹ́ san kún un. (Léfítíkù 27:31) Ọlọ́run tún pàṣẹ pé kí wọ́n máa san “ìdá mẹ́wàá ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran.”—Léfítíkù 27:32.
Tí wọ́n bá fẹ́ ṣírò ìdá mẹ́wàá ẹran ọ̀sìn wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ya ẹran kẹwàá sọ́tọ̀ nínú gbogbo ẹran mẹ́wàá tó bá jáde nínú ọgbà ẹran wọn. Òfin náà sọ pé wọn ò gbọdọ̀ yẹ̀ wọ́n wò tàbí pààrọ̀ àwọn ẹran tí wọ́n yà sọ́tọ̀ yìí, wọn ò sì gbọ́dọ̀ sọ ìdá mẹ́wàá ẹran ọ̀sìn wọn di owó. (Léfítíkù 27:32, 33) Àmọ́, wọ́n lè sọ ìdá mẹ́wàá kejì tí wọ́n máa ń san nígbà àjọyọ̀ ọdọọdún di owó. Ìṣètò yìí mú kó túbọ̀ rọrùn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n máa rìnrìn àjò tó jìn kí wọ́n tó dé ibi àjọyọ̀ náà.—Diutarónómì 14:25, 26.
Ìgbà wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń san ìdá mẹ́wàá? Ọdọọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń san ìdá mẹ́wàá. (Diutarónómì 14:22) Àmọ́ ní ọdún keje, ohun tí wọ́n máa ń ṣe yàtọ̀. Ọdún yẹn jẹ́ sábáàtì tàbí ọdún ìsinmi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í gbin ohunkóhun. (Léfítíkù 25:4, 5) Torí pé ọdún yìí yàtọ̀, wọn kì í san ìdá mẹ́wàá nígbà ìkórè. Ní òpin gbogbo ọdún kẹta àti ìkẹfà láàárín ọdún méje tó jẹ́ ọdún sábáàtì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fún àwọn òtòṣì àtàwọn ọmọ Léfì ní ìdá mẹ́wàá kejì tí wọ́n máa ń san lọ́dún.—Diutarónómì 14:28, 29.
Ìyà wo ni wọ́n máa fi jẹ ẹni tí kò bá san ìdá mẹ́wàá? Òfin Mósè kò sọ ìyà tí wọ́n máa fi jẹ ẹni tí kò bá san ìdá mẹ́wàá. Kì í ṣe torí kí wọ́n má bàa fìyà jẹ wọ́n ni wọ́n ṣe ń san ìdá mẹ́wàá, wọ́n máa ń san án torí wọ́n mọ̀ pé ohun tó yẹ káwọn ṣe nìyẹn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń sọ fún Ọlọ́run pé àwọn ti san ìdá mẹ́wàá àwọn, wọ́n sì máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó bù kún àwọn torí pé àwọn ti ṣe bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 26:12-15) Ọlọ́run gbà pé ẹni tí kò bá san ìdá mẹ́wàá ń ja òun lólè.—Málákì 3:8, 9.
Ṣé ẹrù ìnira ni ìdá mẹ́wàá? Rárá. Ọlọ́run ṣèlérí fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá san ìdá mẹ́wàá, òun máa tú ìbùkún sórí wọn débi pé wọn ò ní ṣaláìní ohunkóhun. (Málákì 3:10) Àmọ́, ìyà máa ń jẹ wọ́n tí wọn ò bá san ìdá mẹ́wàá náà. Ọlọ́run ò ní bù kún wọn mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ṣe làwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì máa ń pa iṣẹ́ àgọ́ ìjọsìn tàbí tẹ́ńpìlì tì, wọ́n á wá lọ ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí àwọn àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì sin Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.—Nehemáyà 13:10; Málákì 3:7.
Bí wọ́n ṣe san ìdá mẹ́wàá nínú Bíbélì—“Májẹ̀mú Tuntun”
Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ìdá mẹ́wàá wà lára ohun táwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa san. Àmọ́ ó ti dópin lẹ́yìn ikú Jésù.
Nígbà ayé Jésù
Nínú apá Bíbélì táwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Tuntun, ó ṣe kedere pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì ń san ìdá mẹ́wàá nígbà ti Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé. Jésù mọ̀ pé ó yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa san ìdá mẹ́wàá, àmọ́ ó bá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wí torí ìwà àgàbàgebè wọn ló jẹ́ kí wọ́n máa san ìdá mẹ́wàá àmọ́ wọn ò “ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin sí, ìyẹn ìdájọ́ òdodo, àánú àti òtítọ́.”—Mátíù 23:23.
Lẹ́yìn ikú Jésù
Bíbélì ò sọ pé ká máa san ìdá mẹ́wàá lẹ́yìn ikú Jésù. Ikú ìrúbọ Jésù ti fòpin sí Òfin Mósè, ó sì ti pa á rẹ́ títí kan àṣẹ tó sọ pé “kí wọ́n máa gba ìdá mẹ́wàá.”—Hébérù 7:5, 18; Éfésù 2:13-15; Kólósè 2:13, 14.
a Ìdá mẹ́wàá jẹ́ “ìpín kan nínú mẹ́wàá lára ohun tó ń wọlé téèyàn yà sọ́tọ̀ fún ohun kan pàtó. . . . Tí wọ́n bá mẹ́nu kan ìdá mẹ́wàá nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń lò ó fún ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn.”—Harper’s Bible Dictionary, ojú ìwé 765.