Ṣé Ilẹ̀ Ayé Máa Pa Run?
Ohun tí Bíbélì sọ
Rárá o, ilẹ̀ ayé ò ní pa run láé, a ò ní finá sun ún, a ò sì ní pààrọ̀ rẹ̀. Ohun tí Bíbélì kọ́ni ni pé Ọlọ́run dá ayé ká lè máa gbé ibẹ̀ títí láé.
“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.
“[Ọlọ́run] fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.”—Sáàmù 104:5.
“Ilẹ̀ ayé dúró . . . fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Oníwàásù 1:4.
“Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in . . . kò wulẹ̀ dá a lásán, . . . ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.”—Aísáyà 45:18.
Ṣé àwọn èèyàn máa lè ba ayé jẹ́?
Ọlọ́run ò ní gbà kí àwọn èèyàn fi ìdọ̀tí, ogun tàbí ohunkóhun míì ba ayé yìí jẹ́ pátápátá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Báwo ló ṣe máa ṣe é?
Ọlọ́run máa fi Ìjọba ọ̀run tó pé láìkù síbì kan, rọ́pò àwọn ìjọba èèyàn tí ò lè dáàbò bo ayé yìí. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10) Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run ló máa jẹ́ ọba Ìjọba yẹn. (Aísáyà 9:6, 7) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi agbára tó ní ṣiṣẹ́ ìyanu láti kápá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá. (Máàkù 4:35-41) Torí pé Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa lágbara dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lórí ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀. Ó máa tún ayé ṣe, tàbí ká kúkú sọ pé ó máa sọ ayé di ọ̀tun, nǹkan á wá rí bó ṣe rí nínú ọgbà Édẹ́nì nígbà yẹn.—Mátíù 19:28; Lúùkù 23:43.
Ṣebí Bíbélì sọ pé a máa finá sun ayé yìí?
Rárá, kò sọ bẹ́ẹ̀. Ohun tó máa ń mú káwọn kan sọ bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ṣi ohun tó wà nínú 2 Pétérù 3:7 lóye, èyí tó sọ pé: “Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná.” Wo kókó pàtàkì méjì tó máa jẹ́ ká lóye ohun tí ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí:
Tí Bíbélì bá lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “ọ̀run,” “ilẹ̀ ayé,” àti “iná”, ó máa ń ní ju ìtumọ̀ kan lọ. Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 11:1 sọ pé: “Gbogbo ilẹ̀ ayé ń bá a lọ láti jẹ́ èdè kan.” Àwọn èèyàn ni “ilẹ̀ ayé” tí ibí yìí sọ ń tọ́ka sí.
Àwọn ẹsẹ tó ṣáájú 2 Pétérù 3:7 jẹ́ ká mọ ohun tí àwọn ọ̀run, ilẹ̀ ayé àti iná tí ẹsẹ keje yẹn dárúkọ túmọ̀ sí. Ẹsẹ 5 àti 6 fọ̀rọ̀ wé Ìkún-omi ìgbà ayé Nóà. Nígbà yẹn, Ọlọ́run pa ayé run, àmọ́ ilẹ̀ ayé wa yìí ò pa run. Ṣe ni Ìkún-omi náà pa àwọn èèyàn oníwà ipá run. Àwọn ni “ayé” tó pa run. (Jẹ́nẹ́sísì 6:11) Ìkún-omi náà tún pa “ọ̀run” run—ìyẹn àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso aráyé ìgbà yẹn. Torí náà, àwọn èèyàn burúkú ló pa run, kì í ṣe ilẹ̀ ayé wa yìí. Nóà àti ìdílé rẹ̀ la ìparun ayé ìgbà yẹn já, wọ́n sì ń gbé láyé lẹ́yìn Ìkún-omi náà.—Jẹ́nẹ́sísì 8:15-18.
Bíi ti òjò tó rọ̀ nígbà Ìkún-omi, àwọn èèyàn burúkú tó wà nínú ayé ni ìparun, tàbí “iná” tó wà nínú 2 Pétérù 3:7 máa fòpin sí, kì í ṣe ilẹ̀ ayé wa yìí. Ọlọ́run ṣèlérí “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” nínú èyí tí “òdodo yóò . . . máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) “Ọ̀run tuntun” tàbí àkóso tuntun, ìyẹn Ìjọba Ọlọrun, ló máa ṣàkóso lórí “ayé tuntun,” tàbí àwùjọ àwọn èèyàn tuntun. Tí Ìjọba yẹn bá ti ń ṣàkóso, ayé máa di párádísè, àlàáfíà á sì jọba.—Ìṣípayá 21:1-4.