Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ “Aláàánú Ará Samáríà”?
Ohun tí Bíbélì sọ
Wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “Aláàánú Ará Samáríà” láti tọ́ka sí ẹni tó múra tán láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ náà jẹyọ nínú ìtàn tàbí àkàwé kan tí Jésù sọ láti fi hàn pé aládùúgbò rere máa ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láìka ìlú tí wọ́n ti wá tàbí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ sí. a
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Àkàwé wo ni Jésù sọ nípa “Aláàánú Ará Samáríà”?
A lè ṣe àkópọ̀ ìtàn tí Jésù sọ náà báyìí: Ọkùnrin Júù kan ń rìnrìn àjò láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò. Bó ṣe ń lọ, ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn olè, wọ́n lù ú, wọ́n sì fi sílẹ̀ nígbà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.
Ọkùnrin Júù kan tó jẹ́ àlùfáà kọjá, lẹ́yìn náà ọkùnrin Júù kan tó jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn tún kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkùnrin tó ń rìnrìn àjò táwọn ọlọ́ṣà ṣe léṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ìlú kan náà ni ọkùnrin tó ń rìnrìn àjò yìí àtàwọn méjì tó kọjá, síbẹ̀ kò sí ìkankan nínú wọn tó dúró láti ràn án lọ́wọ́.
Nígbà tó yá, ọkùnrin kan láti ìlú míì kọjá, ará Samáríà ni. (Lúùkù 10:33; 17:16-18) Torí pé àánú rẹ̀ ṣe é, ó sún mọ́ ọn, ó sì dí àwọn ọgbẹ́ rẹ̀. Ó wá gbé ọkùnrin náà lọ sí ilé ìgbàlejò kan, ó sì bójú tó o títí di ọjọ́ kejì. Lọ́jọ́ kejì, ó san owó fún olùtọ́jú ilé náà kó lè fi tọ́jú rẹ̀, ó tún sọ pé òun máa san ohunkóhun tó bá ná láfikún pa dà fún un.—Lúùkù 10:30-35.
Kí nìdí tí Jésù fi sọ àkàwé yìí?
Jésù sọ ìtàn yìí fún ọkùnrin kan tó rò pé àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹ̀yà tàbí tí wọ́n jọ ń ṣe ìsìn kan náà ni aládùúgbò òun. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù fẹ́ kọ́ ọkùnrin náà ni pé, kì í ṣe àwọn Júù bíi tiẹ̀ nìkan ló yẹ kó kà sí “aládùúgbò” ẹ̀. (Lúùkù 10:36, 37) Kí àwọn tó fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ ni ìtàn yìí ṣe wà nínú Bíbélì.—2 Tímótì 3:16, 17.
Kí ni àkàwé yìí kọ́ wa?
Ìtàn náà kọ́ wa pé aládùúgbò rere máa ń gba tàwọn míì rò. Ó máa ń ran ẹni tó ń jìyà lọ́wọ́ láìka irú ẹni tó jẹ́, ẹ̀yà rẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè tó ti wá sí. Ohun tí aládùúgbò rere bá fẹ́ kí wọ́n ṣe sí òun ló máa ń ṣe sí àwọn míì.—Mátíù 7:12.
Ta ni àwọn ará Samáríà?
Ilẹ̀ tó wà ní àríwá ìlú Jùdíà ni àwọn ará Samáríà ń gbé. Àtọmọdọ́mọ àwọn Júù tó fẹ́ àwọn tí kì í ṣe Júù wà lára àwọn ará Samáríà.
Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, Àwọn ará Samáríà ti dá ẹ̀sìn tiwọn sílẹ̀. Wọ́n fara mọ́ àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, àmọ́ wọn ò fara mọ́ àwọn tó kù.
Nígbà ayé Jésù, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ò gba tàwọn ará Samáríà, wọn ò sì fẹ́ bá wọn da nǹkan kan pọ̀. (Jòhánù 4:9) Àwọn Júù kan tiẹ̀ máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ará Samáríà” láti bú àwọn èèyàn.—Jòhánù 8:48.
Ṣé ìtàn “Aláàánú Ará Samáríà” ṣẹlẹ̀ lóòótọ́?
Bíbélì ò sọ bóyá àkàwé nípa ará Samáríà náà ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Àmọ́ o, Jésù sábà máa ń lo àṣà àti ibi tàwọn èèyàn mọ̀ dáadáa nígbà tó bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè lóye kókó pàtàkì tó wà nínú ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ wọn.
Ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ inú ìtàn náà bá ohun tí ìtàn sọ mu. Bí àpẹẹrẹ:
Ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò ju ogún (20) kìlómítà lọ, ó sì da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kìlómítà kan. Òótọ́ sì ni ohun tí ìtàn náà sọ pé àwọn tó ń rìnrìn àjò lọ sí Jẹ́ríkò máa ń “sọ̀ kalẹ̀ lọ láti Jerúsálẹ́mù.”—Lúùkù 10:30.
Àwọn àlùfáà àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn míì tó ń gbé ní Jẹ́ríkò sábà máa ń rìnrìn àjò gba ọ̀nà yìí tí wọ́n bá ń lọ sí Jerúsálẹ́mù.
Àwọn ọlọ́ṣà sábà máa ń fara pa mọ́ sójú ọ̀nà tó dá yìí, kí wọ́n lè dá àwọn tó ń rìnrìn àjò lọ́nà, pàápàá àwọn tó ń dánìkan rìnrìn àjò.
a Wọ́n tún máa ń pe àkàwé “Ará Samáríà” ní àkàwé “Aláàánú Ará Samáríà”