Ṣó Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà sí Àwọn Ẹni Mímọ́?
Ohun tí Bíbélì sọ
Rárá o. Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run nìkan ló yẹ ká gbàdúrà sí, ká sì máa gbà á lórúkọ Jésù. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbe li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ.” (Mátíù 6:9, Bíbélì Mímọ́) Jésù ò fìgbà kan rí sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n máa gbàdúrà sí àwọn ẹni mímọ́, àwọn áńgẹ́lì tàbí ẹlòmíì yàtọ̀ sí Ọlọ́run.
Jésù tún sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Jésù nìkan ni Ọlọ́run yàn gẹ́gẹ́ bí alágbàwí wa.—Hébérù 7:25.
Ṣó buru tí mo bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run tí mo sì ń gbà á sáwọn ẹni mímọ́?
Nínú Òfin Mẹ́wàá, Ọlọ́run sọ pé: “Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Olọrun owú ni mi.” (Ẹ́kísódù 20:5, Bíbélì Mímọ́) Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà jẹ́ Ọlọ́urn owú? Bó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni pé ó ń “béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” Ọlọ́run ń fẹ́ ká máa darí gbogbo ohun tó bá jẹ́ mọ́ ìjọsìn, tó fi mọ́ àdúrà, sọ́dọ̀ òun nìkan.—Aísáyà 48:11.
Ó máa bí Ọlọ́run nínú tá a bá lọ ń gbàdúrà sí ẹlòmíì, ì báà jẹ́ ẹni mímọ́ tàbí áńgẹ́lì kan mímọ́ kan. Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù fẹ́ jọ́sìn áńgẹ́lì kan, áńgẹ́lì ò gbà á láyè, ńṣe ló sọ pé: ‘Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ tí wọ́n di ẹ̀rí Jésù mú; forí balẹ̀ fún Ọlọ́run.”—Ìfihàn 19:10, Bíbélì Mímọ́.