Ta Ni Màríà Magidalénì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ni Màríà Magidalénì. Ó lè jẹ́ pé lára ìlú Mágídálà (tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Mágádánì), tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun Gálílì, ni orúkọ náà Magidalénì ti wá. Bóyá Màríà ti gbé níbẹ̀ rí.
Màríà Magidalénì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin mélòó kan tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jọ máa ń rin ìrìn àjò tí wọ́n sì máa ń pèsè jíjẹ mímu fún wọn. (Lúùkù 8:1-3) Ó wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n pa Jésù, ó sì wà lára àwọn tó kọ́kọ́ rí i lẹ́yìn tó jíǹde.—Máàkù 15:40; Jòhánù 20:11-18.
Ṣé aṣẹ́wó ni Màríà Magidalénì?
Bíbélì ò sọ pé aṣẹ́wó ni Màríà Magidalénì. Gbogbo ohun tó sọ nípa rẹ̀ ni pé Jésù lé ẹ̀mí èṣù méje jáde lára rẹ̀.—Lúùkù 8:2.
Kí ló wá mú káwọn èèyàn rò pé aṣẹ́wó ni? Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tó ti kú, àwọn kan sọ pé òun ni obìnrin tí Bíbélì ó dárúkọ (tó ṣeé ṣe kó jẹ́ aṣẹ́wó) tó fi omijé rẹ̀ wẹ ẹsẹ̀ Jésù tó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún gbẹ. (Lúùkù 7:36-38) Ṣùgbọ́n, kò sí ẹ̀rí kankan nínú Bíbélì tó fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.
Ṣé “àpọ́sítélì àwọn àpọ́sítélì” ni Màríà Magidalénì?
Rárá o. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì pe Màríà ní “Màríà Magidalénì Mímọ́” àti “àpọ́sítélì àwọn àpọ́sítélì” torí pé òun ló kọ́kọ́ lọ sọ fún àwọn àpọ́sítélì pé Jésù ti jíǹde. (Jòhánù 20:18) Ṣùgbọ́n ìyẹn ò sọ ọ́ di àpọ́sítélì. Kò sì sí ibi tí Bíbélì ti pè é ní àpọ́sítélì.—Lúùkù 6:12-16.
Ìgbà tó kù díẹ̀ kí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni parí ni wọ́n kọ apá tó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì. Síbẹ̀, ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ni àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì tó fọwọ́ ara wọn gbé Màríà Magidalénì sí ipò tó ga. Nínú àwọn ìwé kan tí wọ́n ti kọ láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì àti ìkẹta, èyí tí kìí ṣe apá kan Bíbélì, wọ́n sọ níbẹ̀ pé àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù jowú Màríà. Irú àwọn ìtàn àgbélẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ ò sí nínú Ìwé Mímọ́.
Ṣé ìyàwó Jésù Kristi ni Màríà Magidalénì?
Rárá o. Kódà, Bíbélì mú kó ṣe kedere pé Jésù kò fẹ́yàwó. a
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ṣé Jésù Ṣègbéyàwó? Ṣé Jésù Ní Àwọn Àbúrò?”