Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Ìtumọ̀ “Ojú fún Ojú”?

Kí Ni Ìtumọ̀ “Ojú fún Ojú”?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ọ̀kan lára Òfin tí Ọlọ́run gbẹnu Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyé àtijọ́ ni “ojú fún ojú”, Jésù sì mẹ́nu bà á nínú Ìwàásù orí Òkè. (Mátíù 5:38; Ẹ́kísódù 21:24, 25; Diutarónómì 19:21) Ohun tó túmọ̀ sí ni pé tí wọ́n bá fẹ́ fìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀, ìyà tó yẹ ẹ̀ṣẹ̀ tó dá ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi jẹ ẹ́. a

 Ẹni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ẹlòmíì léṣe ni òfin yìí máa ń mú. Òfin Mósè sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe fún ẹni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ẹlòmíì léṣe, ó ní: “Ìṣẹ́léegun fún ìṣẹ́léegun, ojú fún ojú, eyín fún eyín; irú àbùkù kan náà tí ó lè fà sí ara ẹni náà, ìyẹn ni kí a fà sí ara òun náà.”​—Léfítíkù 24:20.

 Kí nìdí tí òfin “ojú fún ojú” fi wà?

 Òfin “ojú fún ojú” ò fún àwọn èèyàn láṣẹ láti gbẹ̀san ara wọn. Dípò ìyẹn, ṣe ló máa ń ran àwọn adájọ́ tá a yàn sípò lọ́wọ́ láti fìyà tó tọ́ jẹ ẹni tó ṣẹ̀ láìle koko jù, láìsì gbọ̀jẹ̀gẹ́ jù.

 Òfin yẹn tún máa ń jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ẹlòmíì níkà tàbí tó ń gbìmọ̀ àtiṣe bẹ́ẹ̀ ki ọwọ́ ọmọ ẹ̀ bọṣọ. Òfin Mósè ṣàlàyé pé, “Àwọn tí ó kù [ìyẹn, àwọn tó rí bí Ọlọ́run ṣe ṣèdájọ́ òdodo] yóò gbọ́, àyà yóò sì fò wọ́n, wọn kì yóò sì tún ṣe ohunkóhun tí ó burú bí èyí mọ́ láé láàárín rẹ.”​—Diutarónómì 19:20.

 Ṣé àwọn Kristẹni máa ń tẹ̀ lé òfin “ojú fún ojú”?

 Rárá, òfin yìí ò de àwọn Kristẹni. Inú Òfin Mósè ló wà, ikú ìrúbọ tí Jésù kú sì ti fòpin sí i.​—Róòmù 10:4.

 Síbẹ̀, òfin náà jẹ́ ká lóye bí Ọlọ́run ṣe ń ronú. Bí àpẹẹrẹ, ó fi hàn pé onídàájọ́ òdodo ni Ọlọ́run. (Sáàmù 89:14) Ó tún jẹ́ ká rí ìlànà tó fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìdájọ́ òdodo, ìyẹn ni pé ó yẹ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ jìyà “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”​—Jeremáyà 30:11.

 Àṣìlóye táwọn èèyàn ní nípa òfin “ojú fún ojú”

 Àṣìlóye: Òfin “ojú fún ojú” ti le koko jù.

 Òtítọ́: Kì í ṣe pé òfin yẹn fún àwọn adájọ́ láṣẹ láti máa hùwà ìkà torí pé wọ́n fẹ́ dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, tí wọ́n bá lò ó bó ṣe yẹ, ṣe ló máa jẹ́ kí àwọn adájọ́ tó tóótun kọ́kọ́ gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹ̀ wò, kí wọ́n wo ohun tó fà á, kí wọ́n sì wò ó bóyá lóòótọ́ lẹni náà mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó ṣe, kó tó wá di pé wọ́n á fìyà jẹ ẹ́. (Ẹ́kísódù 21:28-30; Númérì 35:22-25) Torí náà, òfin “ojú fún ojú” kì í jẹ́ káwọn adájọ́ ki àṣejù bọ̀ ọ́ tí wọ́n bá fẹ́ fìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.

 Àṣìlóye: Ṣe ni òfin “ojú fún ojú” kàn gbé agbára lé àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti máa gbẹ̀san ara wọn bó ṣe wù wọ́n.

 Òtítọ́: Ohun tí Òfin Mósè fúnra ẹ̀ sọ ni pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí o di kùnrùngbùn sí ọmọ àwọn ènìyàn rẹ.” (Léfítíkù 19:18) Dípò kí Òfin náà gba àwọn èèyàn láyè kí wọ́n máa gbẹ̀san, ṣe ló rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, kí wọ́n sì kọ́wọ́ ti ètò tó ṣe láti fìyà tó tọ́ jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ lábẹ́ òfin.​—Diutarónómì 32:35.

a Òfin yìí, tí wọ́n máa ń pè ní lex talionis lédè Látìn nígbà míì, wà lára òfin táwọn orílẹ̀-èdè míì máa ń tẹ̀ lé láyé àtijọ́.