Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Ẹnì Kejì Ẹ Bá Hùwà Tó Ń Múnú Bí Ẹ

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Ẹnì Kejì Ẹ Bá Hùwà Tó Ń Múnú Bí Ẹ
  •   Ìgbà tí nǹkan bá wù ẹ́ lo máa ń ṣe é; ọkọ tàbí aya rẹ fẹ́ kéèyàn tí múra nǹkan sílẹ̀ kó tó ṣe é.

  •   Èèyàn jẹ́jẹ́ tí kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ ni ẹ́; ọkọ tàbí aya rẹ túra ká ara ẹ̀ sì yá mọ́ọ̀yàn.

 Ṣé ọkọ tàbí aya rẹ máa ń hùwà tó ń múnú bí ẹ? Tó o bá ń ronú nípa ẹ̀ ṣáá, ìyẹn lè fa ìṣòro nínú ìgbéyàwó yín. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “ẹni tó bá ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ṣáá ń tú ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ká.”—Òwe 17:9.

 Dípò tí wàá fi jẹ́ kí ìwà tó ń múnú bí ẹ dá ìjà sílẹ̀ láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ, o lè kọ́ bí wàá ṣe máa fojú tó dáa wo ìwà náà.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Ojú tó yẹ kó o máa fi wo ìwà tó ń múnú bí ẹ

 Ànímọ́ kan tó ń múnú bí ẹ lára ẹnì kejì ẹ lè jẹ́ ànímọ́ kan náà tó o nífẹ̀ẹ́ sí. Ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta yìí:

 “Ọkọ mi máa ń pẹ́ kó tó ṣe nǹkan tán, kì í sì í tètè múra tá a bá fẹ́ lọ síbì kan. Ṣùgbọ́n ìwà rẹ̀ yìí náà ló mú kó jẹ́ onísùúrù, ó sì máa ń ní sùúrù fémi náà. Bó ṣe ń pẹ́ yẹn máa ń bí mi nínú nígbà míì, ṣùgbọ́n ó tún wà lára ohun tó fi ń wù mí.”—Chelsea.

 “Ìyàwó mi kì í fẹ́ kí ohunkóhun wọ́lẹ̀; torí ẹ̀ ó máa ń fẹ́ ṣètò gbogbo nǹkan, ìyẹn sì máa ń bí mi nínú nígbà míì. Ṣùgbọ́n, bó ṣe máa ń kíyè sí gbogbo nǹkan kínníkínní yẹn kì í jẹ́ kí ohunkóhun bá a lójijì.”—Christopher.

 “Ó jọ pé ọkọ mi kì í fi bẹ́ẹ̀ ka nǹkan sí, ìyẹn sì máa ń mú mi rẹ̀wẹ̀sì. Síbẹ̀, bí kò ṣe máyé le yẹn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ tó mú kí n fẹ́ràn rẹ̀. Kì í káyà sókè tá a bá níṣòro, ìyẹn sì máa ń wú mi lórí gan-an.”—Danielle.

 Bí Chelsea, Christopher àti Danielle ṣe sọ, ìwà kan tí ẹnì kejì ẹ ní lè múnú ẹ dùn lápá kan, kí ìwà kan náà sì múnú bí ẹ lójọ́ míì. Bí ọ̀rọ̀ bá sì ti rí bẹ́ẹ̀, kò sí bó o ṣe lè kórìíra apá tó ń múnú bí ẹ láì gbójú fo apá tó dáa.

 Ṣùgbọ́n, àwọn ìwà kan wà tí ò dáa rárá. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àwọn kan máa “ń tètè bínú.” (Òwe 29:22) Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kéèyàn sapá láti mú “gbogbo inú burukú, ìbínú, ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò.” aÉfésù 4:31.

 Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé ṣe ni ìwà kan wulẹ̀ ń múnú bí ẹ, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín . . . kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.”—Kólósè 3:13.

 Lẹ́yìn yẹn, gbìyànjú láti wo ibi tẹ́nì kejì ẹ dáa sí i, àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó fà ẹ́ mọ́ra lára ẹ̀. Ọkọ kan tó ń jẹ́ Joseph sọ pé, “Ṣe ni ẹni tó bá ń ronú ṣáá nípa ìwà tó ń múnú bí i lára ẹnì kejì ẹ̀ dà bí ẹni tó ń wo bí ara dáyámọ́ńdì kan ṣe rí gbágungbàgun ṣùgbọ́n tí kò mọyì bó ṣe ń kọ mànà.”

 Ohun tẹ́ ẹ lè jọ jíròrò

 Kí kálukú kọ́kọ́ ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ jọ jíròrò ìdáhùn yín.

  •   Ṣé ìwà kan wà tí ọkọ tàbí aya rẹ ń hù tó o ronú pé ó máa ń fa ìjà láàárín yín? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwà wo ni?

  •   Ṣé ìwà burúkú ni, àbí ó kàn wulẹ̀ ń múnú bí ẹ?

  •   Ṣé ìwà náà ní ibi tó dáa sí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ibo ló dáa sí, kí sì nìdí tí ìyẹn fi wù ẹ́ lára ìwà ọkọ tàbí aya rẹ?