TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?
Ìyẹ́ Labalábá Cabbage White
Kí labalábá tó lè fò, àwọn iṣan ara rẹ̀ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ móoru, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbára lé agbára oòrùn. Àmọ́, bí ojú ọjọ́ bá tiẹ̀ tutù, labalábá cabbage white ní tiẹ̀ tètè máa ń gbéra fò ju àwọn labalábá tó kù lọ. Kí ló mú kó yàtọ̀?
Rò ó wò ná: Kí àwọn labalábá tó gbéra láti fò, ọ̀pọ̀ wọn máa ń gba oòrùn sára, wọ́n lè pa ìyẹ́ wọn pọ̀ tàbí kí wọ́n na ìyẹ́ wọn. Àmọ́, labalábá cabbage white máa ń na ìyẹ́ tiẹ̀ sókè bí ìgbà téèyàn bá kọ lẹ́tà V. Ìwádìí fi hàn pé ohun tó ṣe yìí máa ń jẹ́ kó lè gba ooru tó pọ̀ sára àti pé tó bá na àwọn ìyẹ́ náà sókè, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n dagun ní ìwọ̀n 17 degrees, èyí ló máa jẹ́ kí ooru láti ara oòrùn lọ tààràtà sáwọn iṣan ara rẹ̀ kó lè gbéra láti fò.
Àwọn tó ṣiṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Exeter lórílẹ̀-èdè England lo ọgbọ́n yìí láti ṣe àwọn páànù solar tó túbọ̀ gbéṣẹ́, tó máa rí bí ìyẹ́ labalábá cabbage white tó rí bíi lẹ́tà V. Nígbà tí wọ́n ṣe é, wọ́n rí i pé oòrùn táwọn páànù náà ń gbà sára fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ìlọ́po méjì ju tàwọn páànù solar pẹrẹsẹ lọ.
Àwọn tó ń ṣèwádìí náà tún kíyè sí pé ara ìyẹ́ labalábá náà máa ń bì gan-an. Wọ́n wá ṣe àwọn páànù solar tó rí bíi lẹ́tà V, tó sì ń bì bíi ti ìyẹ́ labalábá náà. Bí wọ́n ṣe ṣe é yìí jẹ́ kí àwọn páànù náà fúyẹ́, kó sì gbéṣẹ́. Àbájáde ìwádìí yìí mú kí ọ̀jọ̀gbọ́n Richard ffrench-Constant, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ṣèwádìí náà sọ pé “ọ̀nà àrà” tí labalábá cabbage white ń gbà gba ooru sára láti ara oòrùn kọjá àfẹnusọ.
Kí lo rò? Ṣé ẹfolúṣọ̀n ló jẹ́ kí ìyẹ́ labalábá cabbage white rí bíi lẹ́ta V? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?