ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?—Apá 3: Túbọ̀ Jàǹfààní Púpọ̀ Bó o Ṣe Ń Ka Bíbélì
Tó o bá kọ́kọ́ ṣí Bíbélì, wàá rí i pé ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ìyẹn dẹ́rù bà ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, wo Bíbélì bí oríṣiríṣi oúnjẹ tí a kó sórí tábìlì níbi àríyá kan. Ó lè má ṣeé ṣe fún ẹ láti jẹ gbogbo ohun tó o rí lori tábìlì náà, àmọ́ o lè jẹ ohun tó wù ẹ́ tí wàá sì gbádùn ẹ̀.
Bí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà ṣe rí nìyẹn, tó o bá fẹ́ jàǹfààní púpọ̀ nínú Bíbélì “kíkà,” ó yẹ kó o pọkàn pọ̀ sí apá ibi tó o fẹ́ kà. Àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Kí nìdí tó fi yẹ kó o pọkàn pọ̀ tó o bá ń ka Bíbélì?
Bó o bá ṣe ń sapá láti ka Bíbélì tó, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe jàǹfààní púpọ̀ nínú rẹ̀. Wo àpẹẹrẹ yìí ná, tó o ba fi tíì olókùn sínú omi gbígbóná fúngbà díẹ̀, o máa tọró díẹ̀, àmọ́ tó o bá jẹ́ kó pẹ́ nínú omi gbígbóná yẹn á túbọ̀ tọró dáadáa.
Bí ọ̀rọ̀ Bíbélì kíkà náà ṣe rí nìyẹn, kì í ṣe pé ká kàn sáré ka Bíbélì, ó yẹ ká fara balẹ̀ kà á, ká sì ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá à ń kà. Ohun tí ẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà (119) sì ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ronú lé e lórí.”—Sáàmù 119:97.
Àmọ́, ṣé ohun tá a wá ń sọ ni pé ó yẹ kéèyàn fi gbogbo ọjọ́ ka Bíbélì kó sì máa ronú lé e lórí? Rárá o, ohun tá à ń sọ rèé: Onísáàmù náà ń wá àyè kó lè ronú nípa ohun tó ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí sì mú kó lè ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́.—Sáàmù 119:98-100.
“Mo rántí ohun tí mọ́mì mi sọ fún mi nígbà kan pe ‘Ọjọ́ méje lèèyàn ní láàárín ọ̀sẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan la sì máa ń ṣe fún ara wa láàárín ọ̀sẹ̀ yẹn. O ò ṣe wá àyè díẹ̀ fún Jèhófà, ó ṣe tán, òun náà ló fún wa ní gbogbo àkókò yẹn!’”—Melanie.
Tá a bá ń ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì, ó máa jẹ́ ká ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́ tàbí nígbà tá a bá dojú kọ́ ìdẹwò láti ṣe ohun tí ò dáa.
Báwo lo ṣe lè jàǹfààní púpọ̀ tó o bá ń ka Bíbélì?
Ṣètò ohun tó o fẹ́ ṣe. Julia dábàá pé: “Ó máa dáa kéèyàn ní ètò fún Bíbélì kíkà, Kó mọ ohun tó fẹ́ kà, ìgbà tó fẹ́ kà á àti ibi tó fẹ́ kà.”
Jẹ́ kí ibi tó o fẹ́ lò tura. Gianna tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) sọ pé: “Wá ibi tó pa rọ́rọ́, kó o sì jẹ́ káwọn tó kù nínú ìdílé yín mọ̀ nípa ètò tó o ṣe fún Bíbélì kíkà kí wọ́n má bàa dí ẹ lọ́wọ́.”
Tó bá jẹ́ pé orí fóònù lo ti fẹ́ ka Bíbélì, o lè gbé e sí ipò tí ìsọfúnni kò fi ní máa wọlé sórí ẹ̀. O sì lè gbìyànjú èyí tá a tẹ̀ sórí ìwé. Kódà, ìwádìí fi hàn pé téèyàn bá ń ka ohun tí wọ́n tẹ̀ sórí ìwé, ó máa ń jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀, ó sì máa ń tètè yéni ju èyí tá a kà lórí ẹ̀rọ lọ.
“Tí mo bá ń fi fóònù mi kàwé, ó máa ń ṣòro fún mi láti pọkàn pọ̀ torí àwọn ìsọfúnni lè wọlé, iná lè má fi bẹ́ẹ̀ sí lórí fóònù mi tàbí kí Íńtánẹ́ẹ̀tì má ṣiṣẹ́ dáadáa, àmọ́ iná nìkan ni mo nílò láti ka èyí tí wọ́n tẹ̀ sórí ìwé.”—Elena.
Kọ́kọ́ Gbàdúrà. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lóye, kó o rántí, kó o sí jàǹfààní nínú ohun tó o fẹ́ kà látinú Bíbélì.—Jémíìsì 1:5.
Kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ lórí ohun tó o kà. Kó o sì fi iṣẹ́ ti àdúrà ẹ lẹ́yìn. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Tó bá jẹ́ Bíbélì tó wà lórí JW Library lò ń lò tàbí torí ìkànnì, o lè tẹ ẹsẹ Bíbélì kan, wàá rí àlàyé kíkún àti àpilẹ̀kọ tó dá lórí ẹsẹ yẹn.
Lo ìbéèrè. Bi àpẹẹrẹ: ‘Kí ni ohun tí mò ń kà yìí jẹ́ kí n mọ̀ nípa Jèhófà? Kí ni ibi tí mo kà yìí kọ́ mi nípa ìwà àti ìṣe Jèhófà?’ (Éfésù 5:1) ‘Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni mo kọ́ níbi tí mo kà yìí tí mo lè fi ṣèwà hù nígbèésí ayé mi?’ (Sáàmù 119:105) ‘Báwo ni mo ṣe lè fi ohun tí mo kà yìí ran ẹlòmíì lọ́wọ́?’—Róòmù 1:11.
O tún lè bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni ohun tí mo kà yìí ṣe bá ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì mu?’ Ìbéèrè yìí sì ṣe pàtàkì gan-an. Kí nìdí? Ìdí ni pé láti Jẹ́nẹ́sísì títí dé Ìfihàn ló bá ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì mu: Ìyẹn bí Jèhófà ṣe máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ àti pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, ìṣàkóso rẹ̀ ló sì dáa jù.