Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Àkókò Lò?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Àkókò Lò?

 Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa ṣọ́ àkókò lò?

  •   Bí owó ni àkókò rí. Tó o bá ti fi ṣòfò, o ò ní rí i nígbà tó o bá nílò ẹ̀. Àmọ́ tó o bá ṣètò bó o ṣe fẹ́ lo àkókò ẹ, wàá rí i lò bó o ṣe fẹ́, kódà, á tún ṣẹ́ kù láti fi ṣe àwọn nǹkan míì tó o fẹ́ràn!

     Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀lẹ ń fọkàn fẹ́, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò ní nǹkan kan. Bí ó ti wù kí ó rí, àní ọkàn àwọn ẹni aláápọn ni a óò mú sanra.”​—Òwe 13:4.

     Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá ń ṣọ́ àkókò ẹ lò, kò ní jẹ́ kí òmìnira ẹ dín kù, ṣe ló máa jẹ́ kó o túbọ̀ lómìnira.

  •   Ó ṣe pàtàkì kó o mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́ àkókò lò, torí ó máa wúlò fún ẹ tó o bá dàgbà. Kódà, bó o bá ṣe ń lo àkókò ẹ máa pinnu bóyá iṣẹ́ máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ àbí ó máa pẹ́ lọ́wọ́ ẹ. Ìwọ náà rò ó, tó o bá jẹ́ ọ̀gá iléeṣẹ́ kan, ṣé o ò ní wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ kan tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló máa ń pẹ́ débi iṣẹ́?

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.”​—Lúùkù 16:10.

     Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Bó o bá ṣe ń lo àkókò sí máa fi irú ẹni tó o jẹ́ hàn.

 Àmọ́ ká sòótọ́, kì í rọrùn láti ṣọ́ àkókò lò. Wo àwọn ohun kan tó lè jẹ́ kó ṣòro.

 Ìṣòro #1: Àwọn ọ̀rẹ́

 “Táwọn ọ̀rẹ́ mi bá ní ká jọ jáde, kódà kí n má fi bẹ́ẹ̀ ráyè, mo máa ń fẹ́ rí i pé mo tẹ̀ lé wọn. Mo máa ń rò ó pé, ‘Tí n bá pa dà dé, màá sáré ṣe àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ṣe jàre.’ Àmọ́ gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń rí bí mo ṣe rò, ó sì ti ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́.”​—Cynthia.

 Ìṣòro #2: Àwọn ohun tó ń pín ọkàn níyà

 “Baba ńlá ìdẹwò ni tẹlifíṣọ̀n. Àwọn eré àtàwọn fíìmù kan wà tó jẹ́ pé ṣe ló máa ń múùyàn mọ́lẹ̀, kì í rọrùn láti jára ẹni gbà.”​—Ivy.

 “Ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo máa ń fi ṣòfò tí mo bá ti ń tẹ fóònù. Ó máa ń dùn mí pé ó dìgbà tí fóònù ọ̀hún bá kú kí n tó fi sílẹ̀.”​—Marie.

 Ìṣòro #3: Fífòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la

 “Tó bá di pé kí n ṣe àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n fún wa níléèwé tàbí tí mo fẹ́ ṣe ohunkóhun míì tó yẹ kí n ṣe, ṣe ni mo máa ń fòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la. Màá wá máa fi àkókò mi ṣòfò lórí ohun tí ò ní láárí títí á fi wá bọ́ sórí fún mi láti parí iṣẹ́ àṣetiléwá mi. Ẹ ò rí i pé ìyẹn kù díẹ̀ káàtó.”​—Beth.

Tó o bá ń ṣọ́ àkókò ẹ lò, kò ní jẹ́ kí òmìnira ẹ dín kù, ṣe ló máa jẹ́ kó o túbọ̀ lómìnira

 Ohun tó o lè ṣe

  1.   Ṣàkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ tó o fẹ́ ṣe. Lára ẹ̀ ni àwọn iṣẹ́ ilé àti iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n fún ẹ níléèwé. Kọ iye àkókò tí ìkọ̀ọ̀kan wọn máa gbà ẹ́ lọ́sẹ̀ kan.

     Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:​10.

  2.   Kọ àwọn ohun tó máa wù ẹ́ kó o ṣe tọ́wọ́ ẹ bá dilẹ̀. Ó lè jẹ́ lílo ìkànnì àjọlò àti wíwo tẹlifíṣọ̀n. Tún kọ iye wákàtí tó o máa ń lò lórí ìkọ̀ọ̀kan wọn láàárín ọ̀sẹ̀ kan.

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n . . . , ẹ máa ra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín.”​—Kólósè 4:5.

  3.   Ṣètò bó o ṣe fẹ́ lo àkókò ẹ. Wo àwọn àkọsílẹ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó o ti ṣe ṣáájú. Ṣé àkókò tó o pín fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì máa tó? Àbí wàá dín àkókò tó o fẹ́ fi gbafẹ́ kù?

     Àbá: Ṣe àkọsílẹ̀ ohun tó o máa ṣe lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, kó o máa sàmì sí ìkọ̀ọ̀kan tó o bá ṣe ń parí ẹ̀.

     Ìlànà Bíbélì: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.”​—Òwe 21:5.

  4.   Gbé ìgbésẹ̀. Ká sòótọ́, ó lè gba pé kó o má ráyè bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ jáde tàbí gbafẹ́ lásìkò kan torí kó o lè ráyè ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì. Àmọ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, wàá rí i pé o túbọ̀ rí àyè ìgbafẹ́, wàá sì túbọ̀ gbádùn ẹ̀.

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín.”​​—Róòmù 12:11.

  5.   Fúnra ẹ ní kóríyá lákòókò tó tọ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tara sọ pé, “Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé tí mo bá ti parí méjì nínú àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe lọ́jọ́ kan, màá rò ó pé, ‘Jẹ́ n wo tẹlifíṣọ̀n ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kí n tó máa báṣẹ́ lọ.’ Ni ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún á bá di ọgbọ̀n ìṣẹ́jú mọ́ mi lọ́wọ́, ká tó wí ká tó fọ̀, ó ti di wákàtí kan, kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, mo ti fi wákàtí méjì ṣòfò nídìí tẹlifíṣọ̀n!”

     Ohun tó o lè ṣe ni pé ìgbà tó o bá parí iṣẹ́ tó o fẹ́ ṣe lọ́jọ́ kan ni kó o tó gbafẹ́ láti ṣe kóríyá fúnra ẹ. Má wò ó pé o parí iṣẹ́ o, o ò parí iṣẹ́ o, o lè gbafẹ́ tó bá wù ẹ́.

     Ìlànà Bíbélì: “Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó . . . jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”​—Oníwàásù 2:​24.