Àwòrán Àwọn Ilẹ̀ Inú Bíbélì
Nínú ìwé Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà, wàá rí àwòrán àwọn ilẹ̀ inú Bíbélì tá a ṣàlàyé lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́. O sì lè lò ó tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ ilẹ̀ àti ìlú ni Bíbélì mẹ́nu kan. Torí náà, ìwé yìí á jẹ́ kó o túbọ̀ gbádùn Bíbélì kíkà rẹ. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà máa jẹ́ kó o lè fojú inú wo ibi táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti wáyé nínú Bíbélì. Á sì tún jẹ́ kó o lóye ìdí táwọn ohun kan fi ṣẹlẹ̀ láwọn ibi tí Bíbélì mẹ́nu kàn.
Onírúurú àtẹ àti àwòrán ilẹ̀ tó rí mèremère ló wà nínú ìwé Wo “Ilẹ̀ Dáradára.” Yàtọ̀ síyẹn, onírúurú àwọn àwòrán míì, títí kan àwọn èyí tá a fi kọ̀ǹpútà yà ló wà nínú ẹ̀, àwọn nǹkan yìí sì máa jẹ́ ká túbọ̀ gbádùn Bíbélì kíkà.
Àwòrán ilẹ̀ inú Bíbélì yìí máa jẹ́
kó o lóye ìrìn àjò Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù
kó o rí ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà láti Íjíbítì títí dé Ilẹ̀ Ìlérí
kó o rí báwọn ọ̀tá ṣe yí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ká
kó o rí àwọn ibi tí Jésù wàásù dé nígbà tó wà láyé
kó o rí ibi táwọn ìjọba alágbára kan nasẹ̀ dé, irú bí ìjọba Bábílónì, Gírí ìsì àti Róòmù
Wàá rí ìwé yìí lọ́fẹ̀ẹ́ lórí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower.