Ta Ló Dá Ẹ̀sìn Yín Sílẹ̀?
Ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní bẹ̀rẹ̀ ní òpin ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún. Nígbà yẹn, àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kékeré kan tó ń gbé nítòsí ìlú Pittsburgh, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ. Wọ́n fi àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì wé ohun tí Bíbélì fi ń kọ́ni. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ohun tí wọ́n kọ́ jáde nínú àwọn ìwé, ìwé ìròyìn àti nínú ìwé àtìgbàdégbà tá à ń pè nísinsìnyí ní Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà.
Ọkùnrin kan wà nínú àwùjọ àwọn olóòótọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Charles Taze Russell. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Russell ló ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn tó sì jẹ́ olótùú àkọ́kọ́ fún ìwé ìròyìn The Watchtower, síbẹ̀ kì í ṣe olùdásílẹ̀ ẹ̀sìn tuntun. Ohun tó jẹ́ àfojúsùn Russell àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí a ti mọ̀ wọ́n sí nígbà yẹn ni pé kí wọ́n gbé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi ga kí wọ́n sì máa ṣe ohun tí ìjọ Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe. Nítorí pé Jésù ló dá Ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀, òun náà la mọ̀ pé ó dá ètò ẹ̀sìn wa sílẹ̀.—Kólósè 1:18-20.