Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì
A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.
A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.
Australia
Wíwo Ọgbà Wa Yíká
Monday sí Friday
8:30 àárọ̀ sí 11:00 àárọ̀ àti 1:00 ọ̀sán sí 4:00 ìrọ̀lẹ́
Ó máa gba wákàtí kan
Jọ̀ọ́, pè kó o tó wá wò yíká ọgbà wa
Àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe níbẹ̀
Ẹ̀ká yìí ló ń bójú tó bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní orílẹ̀-èdè American Samoa, Australia, the Cook Islands, New Zealand, Niue, Norfolk Island, Samoa, Timor-Leste àti Tonga. Wọ́n tún ń bójú tó bá a ṣe ń tú àwọn ìwé tó dá ló’ri Bíblélì sí èdè mẹ́rìnlélógún [24].
Àwọn Àtẹ Tó Ń Sọ Ìtàn Tó O Lè Wò Fúnra Ẹ
Monday sí Friday
8:00 àárọ̀ sí 5:00 ìrọ̀lẹ́
Ó máa gba nǹkan bíi wákàtí kan
Wàá rí ìtàn bí iṣẹ́ ìwáàsù ṣe ń tẹ̀síwájú ní Australasia.