Àlùfáà Kan Rí Ìdáhùn sí Ìbéèrè Rẹ̀
Lọ́jọ́ kan, obìnrin kan tó ń jẹ́ Eliso, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì obìnrin kan tó ní kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ nílé rẹ̀, ni obìnrin yẹn bá gba àlejò kan tí kò retí. Àlùfáà kan àti ìyàwó rẹ̀ ni wọ́n wá bá a lálejò. Eliso ti gbọ́ pé ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí tọkọtaya náà bí ṣẹ̀ṣẹ̀ kú ni.
Bí Eliso ṣe ń fi tọkàntọkàn bá wọn kẹ́dùn ọmọ wọn tó kú náà, ṣe ni àlùfáà náà àti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún gan-an. Àlùfáà náà fìbínú sọ pé: “Mi ò mọ̀dí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú àdánwò yìí! Báwo ló ṣe máa mú ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí mo bí lọ? Ọdún kejìdínlọ́gbọ̀n (28) rèé tí mo ti ń sin Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ ohun rere ni mo ti ṣe fáwọn èèyàn, ṣé bó ṣe máa san mí lẹ́san rèé! Kí ló dé t’Ọ́lọ́run pa mí lọ́mọ?”
Eliso ṣàlàyé fún tọkọtaya náà pé Ọlọ́run kọ́ ló mú ọmọ wọn lọ. Ó tún bá wọn sọ̀rọ̀ lórí àkòrí bí ìràpadà, àjíǹde àti ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba kí nǹkan búburú máa ṣẹlẹ̀. Àlùfáà náà àti ìyàwó rẹ̀ sọ fún Eliso pé ó ti jẹ́ kí àwọn rí ìdáhùn sáwọn ohun tí wọ́n ń gbàdúrà fún.
Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, àlùfáà yìí àti ìyàwó rẹ̀ lọ dara pọ̀ mọ́ obìnrin náà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Àkòrí tó sọ pé “Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú,” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ni Eliso ń jíròrò pẹ̀lú ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Tọkọtaya náà sì lóhùn sí ìjíròrò náà dáadáa.
Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì lọ sí àkànṣe àpéjọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nílùú Tbilisi, lórílẹ̀-èdè Georgia. Ó wú wọn lórí gan-an nígbà tí wọ́n rí ojúlówó ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti gbìn sọ́kàn àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì wọn, àmọ́ tí wọn ò rí i ṣe.