Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n Fi Fóònù Tó Wà fún Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ọ̀pọ̀ Lẹ́kọ̀ọ́

Wọ́n Fi Fóònù Tó Wà fún Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ọ̀pọ̀ Lẹ́kọ̀ọ́

 Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù ni Daiane, orílẹ̀-èdè Brazil ló sì ń gbé. Lọ́jọ́ kan tó ń wàásù lórí fóònù, ó bá tọkọtaya kan sọ̀rọ̀, wọ́n sì gbádùn ohun tó bá wọn sọ. Wọ́n wá sọ fún Daiane pé àwọn máa tó kó lọ sí abúlé kan tó jìnnà, kò sì síná mọ̀nàmọ́ná àti Íńtánẹ́ẹ̀tì níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbẹ̀. Kí wọ́n lè máa bá ìjíròrò Bíbélì náà lọ, wọ́n fún Daiane ní nọ́ńbà fóònù kan tó wà fún gbogbo èèyàn lábúlé náà, wọ́n sì jọ ṣàdéhùn ọjọ́ àti àkókò tí wọ́n á jọ sọ̀rọ̀.

 Daiane wá pe fóònù náà lákòókò tí wọ́n jọ fàdéhùn sí, tọkọtaya náà sì gbé e! Kódà, ẹ̀ẹ̀mẹta ni wọ́n tún jọ sọ̀rọ̀ lórí fóònù náà láàárín ọ̀sẹ̀ méjì tó tẹ̀ lé e.

 Àmọ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn, tí Daiane bá pè, tọkọtaya náà kì í gbé fóònù mọ́. Síbẹ̀, Daiane ò jẹ́ kó sú òun, ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀ ló máa ń pe fóònù náà, ó sì máa ń wàásù fún ẹnikẹ́ni tó bá gbé e. Nípa bẹ́ẹ̀, Daiane bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn mélòó kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní abúlé náà.

 Lọ́jọ́ kan, bí Daiane àti ọkọ ẹ̀ ṣe ń kọ́ ọkùnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí fóònù yẹn, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan ní abúlé náà fetí kọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Ló bá sún mọ́ ọkùnrin náà kó lè gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ dáadáa. Ni àlùfáà náà bá sọ pé òun fẹ́ bá Daiane àti ọkọ ẹ̀ sọ̀rọ̀. Ó gbádùn ohun tí wọ́n jọ sọ lọ́jọ́ yẹn débi tó fi sọ pé òun náà fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Daiane àti ọkọ ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn mẹ́fà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí fóònù kan náà ní abúlé yẹn, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì náà sì wà lára wọn. Kódà, díẹ̀ nínú wọn ti fi fóònù tó wà lábúlé yẹn dara pọ̀ mọ́ ìpàdé wa. Ọ̀kan nínú wọn tiẹ̀ ṣe àga kan síbi fóònù náà, káwọn tó bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lè ríbi jókòó sí.

 Inú Daiane àti ọkọ ẹ̀ dùn pé àwọn láǹfààní láti wàásù ní abúlé tó jìnnà yìí. Daiane sọ pé, “Jèhófà mọ bó ṣe lè mú kí ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn láìka bí ibi tí wọ́n ń gbé ṣe jìnnà tó.”