Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú Lórílẹ̀-èdè Guyana
Joshua tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tó sì ti sìn fúngbà díẹ̀ lórílẹ̀-èdè Guyana sọ pé: “Ayọ̀ tí mo ní nígbà tí mo lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i kọjá àfẹnusọ!” Ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sìn ní Gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà táwọn èèyàn ti fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ló láyọ̀ bíi ti Joshua. a Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè kọ́ lára àwọn tó lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i yìí? Tó bá wù ẹ́ láti lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè, báwo làwọn ẹ̀kọ́ tó o kọ́ yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè múra sílẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
Kí Ló Mú Kí Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn?
Kí arákùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Linel tó kó lọ sórílẹ̀-èdè Guyana, ó ti kọ́kọ́ lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Àwùjọ èèyàn tó tó ogun ni wọ́n yàn sí ìpínlẹ̀ West Virginia. Iṣẹ́ ìwàásù àti ìfararora tí mo gbádùn fún ọ̀sẹ̀ méjì nílùú yẹn ti yí ìgbésí ayé mi pa dà! Mo ti jẹ́ kí ìpinnu mi túbọ̀ lágbára pé Jèhófà ni máa fi gbogbo ayé mi sìn.”
Tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Garth àti Erica ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bí wọ́n ṣe máa lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè, orílẹ̀-èdè Guyana sì ni wọ́n yàn. Kí nìdí? Erica sọ pé: “Èmi àti ọkọ mi mọ tọkọtaya kan tó lọ sìn síbẹ̀. Ìtara àti ìfẹ́ tí wọn fi ń ṣiṣẹ́ ló mú kó wù wá láti lọ síbẹ̀.” Erica àti Garth gbádùn ọdún mẹ́ta tí wọ́n lò níbẹ̀, wọ́n sọ pè “iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni” ni. Garth sọ pé: “A ti sìn nílẹ̀ òkèèrè, a sì gbádùn ẹ̀ gan-an.” Nígbà tó yá, òun àti ìyàwó ẹ̀ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, orílẹ̀-èdè Bolivia ni wọ́n ti ń sìn báyìí.
Báwo Ni Wọ́n Ṣe Múra Sílẹ̀?
Tá a bá ń fàwọn ìlànà Bíbélì sílò, ó máa mú ká jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn. (Hébérù 13:5) Bíbélì tún kọ wa pé ká máa ronú jinlẹ̀ ká tó ṣe ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé. (Lúùkù 14:26-33) Ìyẹn sì ní nínú bóyá kéèyàn kó lọ sílẹ̀ òkèèrè! Garth sọ pé: “Ká tó kó lọ sórílẹ̀-èdè Guyana, èmi àti Erica ti jẹ́ kí nǹkan díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn. Ìyẹn sì gba pé ká ta ọjà wa, ilé wa, àti gbogbo nǹkan tá ò nílò tá a kó jọ sílé. Ó sì tó ọdún mélòó kan tá a fi ṣèyẹn. Ká má ba à gbọ́kàn kúrò lórí àfojúsùn wa láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè Guyana, ọdọọdún la máa ń ṣèbẹ̀wò síbẹ̀.”
Kókó míì tó yẹ kéèyàn gbé yẹ̀ wò ni owó tó ń wọlé. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ó ṣeé ṣe fáwọn tó lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i láti ṣiṣẹ́ nílẹ̀ òkèèrè torí pé òfin orílẹ̀-èdè náà gbà wọ́n láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn kan máa ń fi kọ̀ǹpútà ṣe irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ láti ilé wọn. Àwọn míì sì máa ń pa dà sórílẹ̀-èdè wọn kí wọ́n lè lọ ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀. Tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Paul àti Sinead máa ń lọ sórílẹ̀-èdè Ireland lẹ́ẹ̀kan lọ́dún láti lọ ṣiṣẹ́. Ètò tí wọ́n ṣe yìí ló jẹ́ kí wọ́n lè sìn lórílẹ̀-èdè Guyana fún ọdún méjìdínlógún (18), àti ọdún méje lẹ́yìn tí wọ́n bí ọmọbìnrin wọn.
Sáàmù 37:5 sọ pé: “Fi ọ̀nà rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀ lé e, yóò sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.” Gbogbo ìgbà ni Christopher àti Lorissa tí wọ́n ń gbé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà máa ń gbàdúrà nípa àfojúsùn wọn láti lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. Nígbà ìjọsìn ìdílé wọ́n, wọ́n tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun táá jẹ́ kí wọ́n lè débi tí wọ́n ń lọ, ìyẹn àǹfààní tí wọ́n máa rí àti ìṣòro tí wọ́n máa ní níbi tí wọ́n ń lọ. Torí pé wọ́n fẹ́ kó lọ́ síbí tí wọn ò ti ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kọ́ èdè míì, wọ́n gbà láti kó lọ sórílẹ̀-èdè Guyana níbí tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì.
Nígbà tó yá, ìlànà tó wà nínú Òwe 15:22 ni wọ́n tẹ̀ lé, ó sọ pé: “Láìsí ìfinúkonú, èrò á dasán, àmọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.” Wọ́n kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè Guyana b láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe ráyè fún iṣẹ́ náà tó àti bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ṣèwádìí nípa ìtọ́jú ìṣègùn tó wà níbẹ̀, bójú ọjọ́ ibẹ̀ ṣe ń máa rí àti àṣà ìbílẹ̀ wọn. Ẹ̀ka ọ́fíìsì dáhùn ìbéèrè wọn, wọ́n sì jẹ́ kí ìgbìmọ̀ alàgbà tó wà lágbègbè ibi tí wọ́n ń bọ̀ mọ̀ nípa wọ́n.
Linel tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ti di alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Guyana báyìí. Kó tó kó lọ síbẹ̀, òun náà tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Òwe 15:22. Ó sọ pé: “Yàtọ̀ sí pé mo tọ́jú owó tí màá fi rìnrìn àjò, mo tún bá àwọn tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ nílẹ̀ òkèèrè sọ̀rọ̀. Mo bá ìdílé mi sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, títí kan àwọn alàgbà ìjọ mi àti alábòójútó àyíká wa. Gbogbo ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù níbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i ni mo kà.”
Ó bọ́gbọ́n mu káwọn tó fẹ́ lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò síbi tí wọ́n fẹ́ kó lọ. Tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Joseph àti Christina sọ pé “Nígbà àkọ́kọ́ tá a lọ sórílẹ̀-èdè Guyana, odindi oṣù mẹ́ta la lò níbẹ̀. Àkókò tá a lò yẹn jẹ́ ká mọ bí ibẹ̀ ṣe rí. Lẹ́yìn tá a pa dà sílé, a ṣètò ara wa, a sì kó lọ síbẹ̀.”
Báwo Lara Wọn Ṣe Mọlé?
Káwọn tó fẹ́ lọ sìn níbi tí àìní ti pọ̀ nílẹ̀ òkèèrè tó lè sin Ọlọ́run dáadáa, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, kí wọ́n sì ṣe tán láti mú ara wọn bá bí nǹkan ṣe rí ládùúgbò ọ̀hún mu, tó fi mọ́ àṣà ìbílẹ̀ ibẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó kúrò lágbègbè olótùútù tí wọ́n sì kó lọ ságbègbè tó móoru ti kíyè sí i pé oríṣiríṣi kòkòrò ló wà níbi tí wọ́n ń gbé báyìí. Joshua tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mi ò tíì ríbi tí ìdun ti pọ̀ tóyẹn rí. “Ó jọ pé orílẹ̀-èdè Guyana ni ìdun pọ̀ sí jù! Àmọ́, nígbà tó yá, ibẹ̀ mọ́ mi lára. Mo tún ti kẹ́kọ̀ọ́ pé tí mo bá ń jẹ́ kí ilé mi mọ́ tónítóní, ìwọ̀nba kòkòrò ló máa wà. Ìyẹn sì gba pé kí n máa fọ abọ́ tó dọ̀tí, kí n máa da ìdọ̀tí nù, kí n sì máa tún ilé ṣe déédéé.”
Tó o bá fẹ́ kára ẹ tètè mọlé lórílẹ̀-èdè tó o kó lọ, ó tún gba pé kó o kọ́ bí wàá ṣe máa jẹ àwọn oúnjẹ tó ò kì í jẹ tẹ́lẹ̀ kó o sì kọ́ bí wọ́n ṣe ń sè wọ́n. Joshua sọ pé: “Èmi àti arákùnrin tá a jọ ń gbé ní káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kọ́ wa bí wọ́n ṣe ń fi àwọn èròjà oúnjẹ ìbílẹ̀ se oúnjẹ. Tá a bá ti mọ bí wọ́n ṣe ń se oúnjẹ ìbílẹ̀ kan, a máa ń pe àwọn ará ìjọ wá sílé wa ká lè jẹ oúnjẹ náà pa pọ̀. Ìyẹn tún ni ọ̀nà míì tá a fi lè túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa ká sì di ọ̀rẹ́ wọn.”
Tó ba kan ti àṣà ìbílẹ̀, Paul àti Kathleen sọ pé: “A kọ́ ọ̀nà táwọn èèyàn gbà pé ó bójú mu láti hùwà àti bó ṣe yẹ kéèyàn máa múra nílẹ̀ olóoru, ìyẹn ò sì mọ́ wa lára tẹ́lẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó gba pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká tó lè ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, síbẹ̀ a ò ṣe ohun tí kò bá ìlànà Bíbélì mu. Bá a ṣe jẹ́ kí àṣà ìbílẹ̀ wọn mọ́ wa lára ti mú káwọn àrá ìjọ túbọ̀ sún mọ́ wa, ó sì ti mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa.”
Àǹfààní Wo Ni Wọ́n Rí?
Joseph àti Christina sọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn tó ṣiṣẹ́ náà, wọ́n sọ pé: “Ìbùkún tó wà nínú iṣẹ́ náà pọ̀ rẹpẹtẹ ju ìṣòro tó lè yọjú. Bá a ṣe gbà láti ṣe ohun tá ò ṣe rí tó sì tún nira yìí tí ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe sàwọn ohun tá a kà sí pàtàkì. Àwọn ohun tá a kà sí pàtàkì tẹ́lẹ̀ kò tún jọ wá lójú mọ́. Gbogbo ìrírí tá a ní ti mú ká túbọ̀ pinnu pé a ò ní jẹ́ kó sú wa láti máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe fún Jèhófà. A ti dẹni tó ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn báyìí.”
Erica tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Bí èmi àtọkọ mi ṣe lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ti jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Jèhófà ti ràn wá lọ́wọ́ lọ́nà tá ò rírú ẹ̀ rí. Àwọn ìrírí tá a sì ní yìí tí mú kí ìgbéyàwó wa túbọ̀ lágbára.”