A Túmọ̀ Ìtẹ̀jáde Sí Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Quebec
Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Quebec (LSQ) ni ọ̀pọ̀ àwọn odi ń sọ ní àpá ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Canada. * Torí pé àwọn odi tó wà níbẹ̀ ò ju ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6000] lọ, ìwọ̀nba ìtẹ̀jáde ló wà ní èdè LSQ. Káwọn èèyàn púpọ̀ sí i bàa lè lóye Bíbélì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe gudugudu méje kí wọn lè ṣe àwọn ìtẹ̀jáde ní èdè LSQ, kí wọ́n sì lè rí i gbà lọ́fẹ̀ẹ́.
Ká bàa lè mọ bí iṣẹ́ ìtúmọ̀ sí èdè yìí ti ṣe pàtàkì tó, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ìtàn Marcel. Ọdún 1941 ni wọ́n bí i sí ìpínlẹ̀ Quebec tó wà lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ó ní àìsàn yírùnyírùn èyí sì mú kó di adití. Marcel sọ pé: “Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án mo bẹ̀rẹ̀ sí i lọ sí ilé ìwé àwọn odi, ibẹ̀ ni mo sì ti kọ́ èdè LSQ. Lóòótọ́, àwọn ìwé kan wà tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn ní èdè adití àmọ́ kò sí àwọn ìtẹ̀jáde ní èdè adití.”
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣe àwọn ìtẹ̀jáde ní LSQ? Marcel dáhùn pé: “Ó máa ń wu àwọn odi láti ní ìsọfúnni ní èdè wọn, ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n lóye ohun tí wọ́n ń kà. Tí kò bá sí ìtẹ̀jáde kankan ní èdè LSQ, ó máa gba pé kí ẹlòmíì ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàlàyé fún wa, ìyẹn kì í sì jẹ́ ká ní ìsọfúnni tó kún tó.”
Kí ìsọfúnni bàa lè wà fún Marcel àtàwọn odi míì tó ń sọ èdè LSQ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ jáde ní èdè LSQ lọ́dún 2005. Láìpé yìí, wọ́n mú kí ọ́fíìsì wọn tó wà ní ìlú Montreal ní ìpínlẹ̀ Quebec gbòòrò sí i. Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún méje ló ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ju méjìlá lọ lọ́ máa ń wá bá wọn ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè mẹ́ta ló wà níbẹ̀, wọ́n sì ní yàrá méjì tí wọ́n ti ń gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀ ní èdè LSQ.
Àwọn tó ń sọ èdè LSQ mọrírì àwọn fídíò ìtẹ̀jáde táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé jáde, wọ́n sì mọyì rẹ̀ gan-an. Stéphan Jacques tó jẹ́ igbákejì olùdarí ẹgbẹ́ Association des Sourds de l’Estrie, * sọ pé: “Mo mọyì bí wọ́n ṣe máa ń ṣe fídíò wọn gan-an. Èdè tí wọ́n lò ṣe kedere, ìrísí ojú wọn sì bá ohun tí wọ́n ń sọ mu, èyí sì dára gan-an. Mo tún mọyì bí àwọn tó wà nínú àwọn fídíò wọn ṣe máa ń múra, wọ́n máa ń múra lọ́nà tó bójú mu.”
Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kẹ́kọ̀ọ́ ní ìpàdé wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lágbàáyé wà lédè LSQ fún ọgọ́rùn-ún méjì àti ogún [220] èèyàn tó ń sọ èdè yẹn, tí wọ́n sì wà ní ìjọ àti àwùjọ méje ní Quebec. * Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ń ṣe àwọn fídíò púpọ̀ sí i lédè LSQ, títí kan àwọn orin tó dá lórí Bíbélì tó sì ń gbé ìgbàgbọ́ ẹni ró.
Inú Marcel tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan dùn gan-an láti rí ìtẹ̀jáde púpọ̀ sí i lédè LSQ. Ó sì mọyì àwọn ìtẹ̀jáde táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe gan-an. Ó ní: “Ìbùkún ńlá ló jẹ́ láti rí fídíò púpọ̀ lédè LSQ lórí ìkànnì jw.org, nígbàkigbà tí mo bá rí àwọn ìsọfúnni yìí lédè mi, inú mi máa ń dùn gan-an!”
^ ìpínrọ̀ 2 Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Quebec ìyẹn LSQ (látinú ọ̀rọ̀ Faransé náà Langue des signes québécoise) ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fara jọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà láwọn apá kan.
^ ìpínrọ̀ 6 Ẹgbẹ́ kan tó ń ṣèrànwọ́ fáwọn odi ní Quebec.
^ ìpínrọ̀ 7 Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ti January 2017 ni àkọ́kọ́ tó jáde lédè LSQ.