Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW BROADCASTING

Wo Fídíò Lórí Apple TV

Wo Fídíò Lórí Apple TV

O lè wo fídíò èyíkéyìí, wàá sì lè dá a dúró, dá a pa dà sẹ́yìn, sún un síwájú tàbí kó bọ́ sí èyí tó kàn. O lè wo fídíò kan ṣoṣo tàbí kó o wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan.

(Àkíyèsí: Rìmóòtù Siri tìẹ lè yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí.)

 Wá Fídíò, Kó O sì Wò Ó

Tẹ Video Categories lókè kó o lè rí àwọn ìsọ̀rí fídíò tó wà.

  • Fìka fa ojú rìmóòtù Siri rẹ kó o lè lọ síbi tó o fẹ́. Àwòrán èyí tó o bá gbé atọ́ka rìmóòtù sí máa tóbi díẹ̀ ju àwọn yòókù lọ.

  • Tẹ ojú rìmóòtù náà kó o lè yan ìsọ̀rí tó o fẹ́.

Àwọn fídíò kan wà tí wàá rí lábẹ́ ìsọ̀rí tó ju ẹyọ kan lọ. Bí àpẹẹrẹ, wàá rí fídíò Ọmọ Onínàákúnàá Pa Dà WáléFídíò, Ìdílé àti Àwọn Ọ̀dọ́.

Tẹ́ bọ́tìnì Shuffle kó o lè máa wo àwọn fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Oríṣiríṣi àkójọ fídíò ló wà ní ìsọ̀rí Wàá rí àwọn fídíò tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kan ní ọ̀wọ́ kan. Àkọlé ìsọ̀rí náà sì máa wà lókè ẹ̀.

  • Tẹ Up àbí Down kó o lè lọ sí ìsọ̀rí tó o fẹ́.

  • Tẹ Left àbí Right kó o lè wo àwọn fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan.

Ọ̀nà méjì lo lè gbà wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan:

  • Tẹ bọ́tìnì Gbádùn Gbogbo Ẹ̀ kó o lè wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan, bẹ̀rẹ̀ látorí àkọ́kọ́.

  • Tẹ bọ́tìnì Shuffle kó o lè máa wo àwọn fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Tó o bá ti wo gbogbo ẹ̀ tán, ó máa dáwọ́ dúró.

Tẹ ojú rìmóòtù kó o lè yan fídíò kan, kó o sì rí Video Details.

Yan ọ̀kan lára àwọn àbá yìí:

  • Gbádùn Ẹ̀: Fídíò náà máa bẹ̀rẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀.

  • Gbádùn Gbogbo Ẹ̀: Wàá lè wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí yẹn, bẹ̀rẹ̀ látorí àkọ́kọ́. Tó o bá ti wo gbogbo ẹ̀ tán, ó máa dáwọ́ dúró.

  • Pa Dà Bẹ̀rẹ̀: Ó máa pa dà bẹ̀rẹ̀ fídíò náà níbi tó o wò ó dé.

Ọ̀wọ́ fídíò tó wà nísàlẹ̀ Video Details ni àwọn fídíò míì tó wà ní ìsọ̀rí tó o wà. Tẹ Down kó o lè lọ sí ìsọ̀rí yẹn, tàbí kó o tẹ Up kó o lè pa dà sí Video Details.

 Ṣe Fídíò Bó O Ṣe Fẹ́

Tó o bá ń wo fídíò kan lọ́wọ́, o lè fi rìmóòtù Siri ẹ ṣe é bó o ṣe fẹ́:

  • Gbádùn Ẹ̀/Dúró Ná: Wàá lè dá fídíò náà dúró. Tó o bá tún tẹ bọ́tìnì yẹn kan náà, ó máa bẹ̀rẹ̀ pa dà. O tún lè tẹ ibi tó sún mọ́ àárín lójú rìmóòtù ẹ kó o lè dá fídíò náà dúró àbí kó o máa wò ó lọ.

  • Pa Dà Sẹ́yìn: Tó o bá ti dá fídíò dúró, fìka fa ojú rìmóòtù sí apá Òsì kó lè pa dà sọ́wọ́ ìbẹ̀rẹ̀ fídíò náà. Tẹ Gbádùn Ẹ̀/Dúró Ná kó o lè máa wò ó lọ.

  • Lọ Síwájú: Tó o bá ti dá fídíò dúró, fìka fa ojú rìmóòtù sí apá Ọ̀tún kó lè lọ sọ́wọ́ ìparí fídíò náà. Tẹ Gbádùn Ẹ̀/Dúró Ná kó o lè máa wò ó lọ.

  • Sún Un Síwájú: Tó o bá fẹ́ kí fídíò fi ìṣẹ́jú àáyá mẹ́wàá lọ síwájú, fìka tẹ apá ọ̀tún ojú rìmóòtù mọ́lẹ̀.

  • Tó o bá ti rí àmì Skip níbi tó o wo fídíò náà dé nísàlẹ̀ ojú tẹlifíṣọ̀n, tẹ ojú rìmóòtù náà.

  • Sún Un Sẹ́yìn: Tó o bá fẹ́ kí fídíò fi ìṣẹ́jú àáyá mẹ́wàá lọ sẹ́yìn, fìka tẹ apá òsì ojú rìmóòtù mọ́lẹ̀.

  • Tó o bá ti rí àmì Skip níbi tó o wo fídíò náà dé nísàlẹ̀ ojú tẹlifíṣọ̀n, tẹ ojú rìmóòtù náà.

  • Menu: Pa dà sí Video Details.

 Wo Fídíò Tó Wà Tàbí Fídíò Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé

Ní ìbẹ̀rẹ̀ JW Broadcasting, wàá rí ìsọ̀rí méjì pàtàkì níbẹ̀:

  1. Àwọn Ohun Tó Wà: Àwọn fídíò tó fani lọ́kàn mọ́ra, bí àwọn èyí tá a máa ń wò nípàdé wa àárín ọ̀sẹ̀ àbí nígbà ìjọsìn ìdílé.

  2. Àwọn Fídíò Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé: Àwọn fídíò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dórí ìkànnì.